Awọn alawo n binu si Buhari, wọn tun ṣepe le awọn to fẹmi awọn ọdọ ṣọfo

Kazeem Aderohunmu

Nile awo kan ti wọn pe ni Tẹmpili Ọsẹ meji niluu Ibadan lawọn ẹlẹsin ibilẹ ti ṣepade laipẹ yii, ohun ti wọn si sọ ni pe, Aarẹ Muhammed Buhari gbọdọ ṣe pẹlẹ, ko yee fọrọ ẹsin ati iwa ẹlẹyamẹya dari Naijiria.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe latigba ti Muhammed Buhari ti ba awọn eeyan orilẹ-ede yii sọrọ ni rogbodiyan ọhun ti dinku, sibẹ, bo ti ṣe kọ ti kọ sọ ohunkohun nipa wahala to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, iwa to ku diẹ kaato ni.

Nibi ipade wọn ọhun, bi awọn ẹlẹsin Ifa ṣe wa nikalẹ, bẹẹ lawọn olooṣa mi-in naa wa nibẹ, ti gbogbo wọn si panu pọ ṣepe nla fawọn to ṣeku pa awọn ọdọ to ṣewọde ta ko SARS.

Ninu atẹjade kan ti wọn fọwọ si ni Aarẹ wọn, Dasọla Fadiran Adefabi, ati akowẹ ẹ, Dokita Fayẹmi Fatunde Fakayọde, pẹlu awọn oloye mẹta mi-in ti sọ pe ohun ibanujẹ ni bi Muhammed Buhari ṣe kọ lati ṣakoso orilẹ-ede yii lọna to le gba fi rọ araalu lọrun. Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe niṣe lo n fi ọrọ ẹsin ati iwa ẹlẹyamẹya da aarin awọn eeyan orilẹ-ede yii ru.

Ẹgbẹ awọn oloriṣa ibilẹ yii fi kun un pe nigba ti ara awọn ko gba a mọ ni ipade pajawiri ṣe waye, tawọn si panu pọ sọ pe, epe lo yẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu bi wọn ti ṣe pa awọn ọdọ to n ta ko ajọ SARS danu.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

One comment

  1. Boseye kori lawon babalawo tiso yen

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: