Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn adari ati ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye, Traditional Religion Worshippers Association (TRWASO), ti fi aidunnu wọn han si bi awọn kan ti wọn pe ara wọn ni alawo kan ṣe ya wọ Fasiti Ifẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Oluọmọ Dokita Oluṣeyi Atanda, ati akọwe wọn, Oloye Ifaṣọla Onifade, fi sita ni wọn sọ pe ẹgbe Trwaso ko lodi si pe ki ẹnikẹni fi ẹhonu han lori ohunkohun to ba n bi i ninu, ṣugbọn ki i ṣe iru ọna ti awọn yẹn gbe tiwọn gba.
Trwaso ṣalaye pe “A gbọ pe awọn eeyan naa n fẹhonu han lori bi wọn ko ṣe yan ọmọ bibi ilu Ileefẹ gẹgẹ bii ọga agba fasiti naa. A mọ pe ẹtọ onikaluuku ni lati binu ti wọn ba ro pe ẹnikan ṣe ohun ti ko tọ fun wọn, ṣugbọn o jẹ ajeji si wa pe aṣọ wa, awọn nnkan ti a n lo, atawọn nnkan miran ni awọn olufẹhonu han naa wọ.
“Lẹyin ti a ṣewadii daadaa, a ri i pe awọn olufẹhonu han naa ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa ni ẹka Ileefẹ, bẹẹ ni wọn ki i ṣe ara ẹka wa lagbegbe yẹn rara.
“Gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye, a ko mọ si bi awọn alaṣẹ ṣe n ṣeto wọn ni Fasiti Ifẹ, a ko si mọ si awọn igbesẹ ti wọn gbe lori yiyan ọga agba fasiti naa, sibẹ, ko si idalare kankan lati fẹhonu han lori igbesẹ naa nitori fasiti ijọba apapọ ni.
“A fẹẹ ke si awọn oṣiṣẹ alaabo lati ṣewadii, ki wọn si foju awọn ti wọn wọ aṣọ bii awa ẹlẹsin abalaye lasiko ti wọn fẹhonu han ni Fasiti Ifẹ han faraye, ki wọn le fimu danrin ofin.
“Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ko mọ nnkan kan nipa ifẹhohu han naa. Iwa ti awọn ti wọn gbe iru igbesẹ bẹẹ hu jẹ iwa imọtara-ẹni ati iwa itiju. Ohun to buru ni pe ṣe ni wọn fẹẹ fi iwa wọn ba wa lorukọ jẹ bii ẹgbẹ ti ko laju, a si n kilọ pe ajeji kankan ko gbọdọ lo awọn nnkan wa mọ.
“A n kilọ fun awọn ti wọn huwa yii lati ma ṣe san aṣọ iru ẹ ṣoro mọ nitori a ko ni i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iru iwa bẹẹ lọjọ iwaju, koda, o le di ọrọ ile-ẹjọ lati le daabo bo orukọ wa.
“A tun n gba ẹnikẹni to ba fẹẹ fẹhonu han lori ohunkohun lati gba ọna to tọ, ki wọn dẹkun iwa to le tapo si aala ẹlomiran. A n tẹnu mọ ọn pe awọn ọmọ ẹgbẹ wa ko lọwọ ninu ifẹhonu han naa, paapaa, nigba ti a ko mọ si nnkan to n bi wọn ninu.
“A nigbagbọ ninu ṣiṣe nnkan lọna to tọ, a ko fara mọ eru ṣiṣe, nitori naa, awa ko lodi si igbesẹ awọn alakoso Fasiti Ifẹ”