Awọn apaniṣowo pa iya agbalagba sinu oko n’Ileṣa, wọn tun yọ oju ẹ lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iya agba ẹni ọdun marundinlaaadọrun kan, Tunmiṣe Oluyẹmi, to n gbe niluu Ileṣa, lawọn apaniṣowo ti dẹmi rẹ legbodo sinu oko rẹ.

Lati ọjọ Satide to kọja lawọn mọlẹbi iya yii ti n wa a kaakiri gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ko too di pe wọn ri oku rẹ ninu oko to n da lagbegbe Fadahunsi, ti awọn amookunṣika naa si ti yọ oju rẹ kan lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe lẹyin ti awọn mọlẹbi ba oku iya yii ninu oko rẹ ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti lọsan-an ọjọ Mọnde.

Ọpalọla ṣalaye pe, “Laago kan ọsan Mọnde lawọn mọlẹbi iya naa, Tunmiṣe Oluyẹmi, lọọ sọ fun awọn ọlọpaa pe awọn ba oku iya ọhun ninu oko rẹ to wa ni Fadahunsi, niluu Ileṣa, ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ naa, ti awọn ti wọn pa a si ti yọ oju rẹ kan lọ.”

O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti awọn ọlọpaa de inu oko naa ti wọn fẹẹ gbe oku ọhun lọ si mọṣuari lawọn ọmọ rẹ yari kanlẹ pe wọn ko gbọdọ gbe e, nitori ṣe lawọn fẹẹ sinku iya awọn kiakia.

Leave a Reply