Faith Adebọla
Bo ba jẹ pe loootọ leeyan n tun aye wa, ko daju pe awọn afurasi adigunjale marun-un kan yoo tun da a labaa lati rin ni bebe ole jija mọ, tori iku gbigbona lawọn eeyan fi da ẹmi wọn legbodo lopin ọsẹ yii. Nibi ti wọn fẹẹ ti ji kẹkẹ Maruwa ẹni ẹlẹni kan gbe ni wọn ka wọn mọ, lawọn bọisi ba fi lilu baye wọn jẹ, lẹyin eyi ni wọn kọrin bọwọ ba tẹ alaṣeju, pipa ni ẹ pa a fun wọn, ni wọn ba dana sun awọn maraarun looyẹ, n ni kaluku ba gbale ẹ lọ.
Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta yii, lọna marosẹ Nkpor Road, nitosi olu-ile-ẹgbẹ Peoples Club, eyi to wa niluu Onitsha, nipinlẹ Anambra.
Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ koro ṣe sọ lori ẹrọ ayelujara, wọn niṣe lawọn gende marun-un ọhun ṣadeede bẹ sidii kẹkẹ Maruwa tẹnikan paaki sẹgbẹẹ titi, wọn ni tọhun n jẹun lọwọ nile ounjẹ kan nitosi ni, afi bawọn jagunlabi yii ṣe fo sinu kẹkẹ ọhun, wọn bẹrẹ si i fa awọn waya rẹ ja, ki wọn le ṣina rẹ, nigba ti ko si kọkọrọ lọwọ wọn.
Ariwo, ‘ole, ole’ ti wọn lẹnikan pa lo mu kawọn bọisi adugbo naa rọ jade, bẹẹ ni wọn lawọn afurasi yii gbiyanju lati ji kẹkẹ naa gbe sa lọ, amọ wọn pada mu wọn.
Lilu ko to wiwọ nigba tọwọ tẹ wọn, wọn ni niṣe ni wọn kọkọ ja wọn sihooho ọmọluabi ki wọn ma baa le sa lọ, lawọn ero pitimu tinu n bi naa ba bẹrẹ si i fi apola igi, okuta, irin ati oriṣiiriṣii nnkan ija ṣe wọn lalejo, igbe ẹbẹ awọn afurasi naa ko si wọ ẹnikẹni leti rara.
Lẹyin ti wọn ti lu wọn lalubami daadaa, tawọn eeyan si ti ro pe wọn yoo fi wọn silẹ, wọn ni niṣe lawọn bọisi kan tun gbẹyin yọ pẹlu taya ati epo bẹntiroolu lọwọ wọn, ni wọn ba fibinu ko awọn afurasi maraarun jọ lori ara wọn, wọn gbe taya kọ ọkọọkan wọn lọrun, bi wọn ṣe n ṣe eyi lọwọ ni wọn lawọn afurasi naa n kigbe ‘Jesu, Jesu’, ti wọn n bẹ awọn eeyan naa pe ki wọn ṣaanu awọn, ki wọn feyi fa awọn leti, amọ ẹyin igba ni wọn n yin agbado arọwa naa si, tibinu-tibinu ni wọn fi bu bẹntiroolu si wọn lara, wọn si dana sun wọn rau.
Ninu ọkan lara awọn fidio ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ ọhun, a ri i bi wọn ṣe n gbe awọn afurasi naa sori ara wọn, lẹyin ti wọn ti lu wọn bii kiku bii yiye, ketekete ni igbe awọn afurasi ole naa n dun bi wọn ṣe n lọgun, ti wọn n kigbe ‘Jesu, Jesu’, ti wọn si n bẹbẹ, bẹẹ lariwo ina la lojiji, nigba ti bẹntiroolu muna, ti wọn si jona gburugburu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn araalu tinu n bi ti dana sun awọn afurasi naa kawọn agbofinro too debẹ, awọn o si ti i ri ẹnikẹni mu lori iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo parọwa sawọn eeyan pe bo tilẹ jẹ pe asiko yii le koko bii oju ẹja loootọ, tara si n kan awọn eeyan, sibẹ, ko tọna, ko si bofin mu, lati maa ṣedajọ ọwọ ara-ẹni fawọn afurasi, bẹẹ lofin ko faaye gba idajọ oju-ẹsẹ, tori ẹni to ba ṣe bẹẹ tun ti lufin iwa ọdaran, yoo si jiya tọwọ ba to o.