Awọn araalu kọyin sofin konile-o-gbele ti Ganduje ṣe, wọn ya sigboro lati dawọọ idunnu ẹgbẹ NNPP to wọle

Monisọla Saka

Awọn olugbe ipinlẹ Kano ti rọ ofin konile-o-gbele ti gomina ipinlẹ naa, Abdullahi Ganduje, ṣe da ṣẹgbẹẹ kan, wọn si ti fọn jade ni origun mẹrẹẹrin ilu naa lati dawọọ idunnu, ti wọn si n yayọ oriire ijawe olubori oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP), Abba Yusuf, to waye lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ yii.

Abba Yusuf to fẹyin ẹni ti wọn jọ n figagbaga, Alaaji Nasiru Gawuna, ti i ṣe igbakeji gomina ipinlẹ naa, lati inu ẹgbẹ oṣelu APC janlẹ, lawọn alatilẹyin ẹ tori ẹ fọn sigboro lati yọ ayọ idunnu eeyan wọn to wọle ibo.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu NNPP mu pupọ ninu ipo sile aṣofin agba ati ti ipinlẹ naa. Ni kete ti wọn ti kede ẹni to wọle ibo ni Gomina Ganduje ti kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade lati aarọ kutukutu titi di alẹ gbèré, ko sẹni to le sọ boya nitori igbakeji rẹ ti ko rọwọ mu lo fi paṣẹ yii. Ohun to kan sọ pe o fa aṣẹ yii ni lati ri i pe ko si idaluru nibikibi, ati pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ labẹ ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, gomina naa ni awọn ṣe ofin konile-o-gbele yii, nitori kawọn eeyan ma baa ṣẹ sofin, nibi ti wọn ba ti n da wahala silẹ kiri latari esi idibo gomina ati tawọn aṣofin ipinlẹ ti wọn ṣẹṣẹ kede.

Amọ ṣa o, lai fi ti gomina ṣe, niṣe lawọn eeyan ilu Kano ya saarin ilu laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, lati dawọọ idunnu bi ẹgbẹ oṣelu NNPP ṣe gbegba oroke ninu ibo sipo gomina ati tawọn aṣofin ipinlẹ.

Niṣe ni wọn n jo, ti wọn n sare kitikiti pẹlu oniruuru orin iṣẹgun lẹnu wọn. Bakan naa ni wọn tun gbe oriṣiiriṣii patako ati beba nla fẹrẹgẹdẹ ti wọn kọ awọn ọrọ loniran-n-ran si dani.

Bi awọn kan ṣe gbe mọto, lawọn mi-in gun ọkada, ọpọlọpọ lo si n fẹsẹ rin gẹgẹ bi wọn ṣe n wọ ilu naa kiri pẹlu ayọ ati idunnu.

Lara oriṣiriṣii ọrọ ti wọn kọ sara awọn nnkan ti wọn gbe dani ni “Aliamudulilai, ti Kwankwaso ni Kano n ṣe”. Omi-in tun kọ ọ pe, “Atilẹyin fun Abba Gida-Gida fun itẹsiwaju ipinlẹ yii”, atawọn mi-in bẹẹ.

Awọn ọlọkada ati oni Maruwa paapaa ko gbẹyin, awọn ni wọn n fi awọn nnkan ọkọ wọnyi dara, ti iran wọn si dun un wo pẹlu bi gbogbo wọn ṣe de fila pupa yanyanyan lọ bii rẹrẹ.

Leave a Reply