Rẹpẹtẹ lawọn èèyàn ya sita lati fẹhonu hàn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ti wọn si sọ pe ẹyin ijọba Rotimi Akeredolu to ni ki awọn Fulani darandaran kuro l’Ondo lawọn wa ni tawọn.
Awọn agbẹ, awọn aṣọgbo atawọn onimọto pẹlu awọn araalu ni kaluku wọn kọ iwe pelebe pelebe lọwọ, ti wọn n sọ pe o to gẹẹ, ki awọn Fulani darandaran maa lọ, nitori pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn lawọn èèyàn yii ti ṣẹmi wọn lofo, ti wọn sì tún ti ji ọpọ gbe pẹlu.
Wọn láwọn fara mọ igbesẹ Gomina Rótìmí Akeredolu lori ki eto aabo to péye le wa.
Wọn ni ti eto aabo to péye ko ba tete waye, o ṣee ṣe ko da wahala àìsí oúnjẹ atawọn inira mi-in silẹ nipinlẹ ohun.
Ìjọba Ondo ti pàṣẹ fawọn Fulani darandaran pe wọn gbọdọ fi ipinlẹ naa silẹ laarin ọjọ meje. Latigba ti iroyin ọhun ti jade ni kaluku ti n sọ ohun ti wọn ri sí i.