Awọn dokita Ekiti yari, wọn ni ijọba ko bikita nipa eto ilera

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ awọn dokita ijọba nipinlẹ Ekiti, National Association of Government General and Medical Dental Practitioners (NAGGMDP), ti sọ pe awọn ko ni i fopin si iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ nitori ijọba ko bikita nipa ẹka eto ilera.

Nibẹrẹ ọsẹ yii ni ẹgbẹ naa, nipasẹ Dokita Kọlawọle Adeniyi to jẹ alaga wọn, kede pe iyanṣẹlodi tawọn gun le ni bii ọsẹ mẹta sẹyin waye nitori bi ijọba ko ṣe gbe awọn igbesẹ ti yoo ran awọn oṣiṣẹ eto ilera atawọn ileewosan to wa nipinlẹ naa lọwọ.

Adeniyi ṣalaye pe ipo ti awọn ọsibitu ijọba mọkandinlogun, ileewosan ikọṣẹmọṣẹ mẹta ati gbogbo awọn ileewosan alabọọde to wa nijọba ibilẹ kaakiri Ekiti wa ko bojumu, dipo kijọba si wa nnkan ṣe, eto adojutofo ẹka ilera ni wọn ṣagbekalẹ laipẹ yii lai tọju awọn ti yoo mu un ṣaṣeyọri.

O sọ ọ di mimọ pe awọn dokita tiẹ ti n fi ipinlẹ Ekiti silẹ lati lọ sibi ti nnkan ti daa, paapaa lasiko ti arun Koronafairọọsi sọ iṣẹ naa di eyi to lewu gidigidi yii.

Adeniyi ni,’’Idi niyi ta a fi n ke si gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ wa lati ba wa sọ fun ijọba ki wọn gbọ nnkan ta a n sọ ki ẹka eto ilera too wo.

‘‘Fun apẹẹrẹ, marun-un ninu awọn ọsibitu ipinlẹ yii ni dokita kọọkan, nigba tawọn ọsibitu ikọṣẹmọṣẹ mẹtẹẹta ni dokita mẹfa si meje.

‘‘Ninu awọn dokita ogun tijọba gba loṣu kejila, ọdun 2015, marun-un pere lo ku. Ninu awọn ogun ti wọn tun gba lọdun 2018, mẹfa lo ku.

‘‘Bakan naa lo jẹ pe awọn dokita akọṣẹmọṣẹ ogun ti wọn gba ni 2016 ku marun-un bayii, awọn to ku si n wa ọna lati lọ.’’

Adeniyi waa sọ pe ọpọ awọn dokita to ku yii ni wọn ti fẹẹ fẹyinti, awọn ọmọde inu wọn ko pọ, eyi yoo si da wahala nla silẹ laipẹ.

Leave a Reply