Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ileeṣẹ DSS, iyẹn awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti mu Oloye Sunday Igbo. Orileede Olominira Benin la gbọ pe wọn ti mu un.
![](https://alaroye.org/wp-content/uploads/Sunday-Igboho-3-300x184.jpg)
Ọjọ Aje, Mọnde, la gbọ pe wọn mu ọkunrin yii. Awọn otẹlẹmyẹ orileede naa la gbọ pe wọn mu un lasiko to n gbiyanju lati fi orileede naa silẹ. A gbọ pe o ti de papaọ ofurufu ko too di pe wọn ko o ni papamọra.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii , la gbọ pe wọn yoo gbe e wa si orileede Naijiria.