Awọn ẹṣọ alaabo fibọn fọ ẹsẹ Raheem to n lọ jẹẹjẹ ẹ l’Ado-Awaye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi wọn ṣe yinbọn mọ okunrin agbẹ kan nigboro ilu naa, Alado tilu Ado-Awaye, Ọba Ademọla Fọlakanmi, ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati ba awọn agbofinro to wa lagbegbe naa sọrọ.

Eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst, iyẹn ikọ to ko awọn agbofinro bii ṣọja, ọlọpaa, sifu difẹnsi ati bẹẹ bẹẹ lọ sinu, eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ da silẹ lati maa mojuto eto aabo nipinlẹ naa ni wọn yinbọn mọ ọkunrin agbẹ ọhun to n jẹ Semiu Raheem, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ede-aiyede kan to bẹ silẹ laarin awọn agbofinro yii pẹlu awọn eeyan kan ti a ko ti i mọ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lo fa ibọn ti awọn agbofinro ọhún yin.

Asiko ti wọn yinbọn yii jẹ igba ti Raheem pẹlu ọrẹ ẹ kan n gun ọkada kọja lọ. Nibi ti wọn ti n gun ọkada wọn gba aarin awọn agbofinro naa kọja ni ibọn ti ọkan ninu wọn yin lasiko naa ti ba ọkunrin agbẹ naa.

Awọn araalu Ado-Awaye to sọrọ lori iṣẹlẹ yii fidi ẹ mulẹ pe ohun ti awọn Operation Burst n foju awọn ri loju ọna ti wọn maa n duro si yii ko dẹrun. Wọn ni niṣe ni wọn maa n paṣẹ fun gbogbo ọlọkada lati sọ kalẹ lori alupupu wọn, ki wọn si wọ ọkada wọn gba ibi ti wọn ti maa n gbegi dina naa kọja.

Yatọ sí eyi, wọn lawọn gabofinro yii fẹran lati maa fipa gbowo lọwọ awọn awakọ, paapaa, awọn to ba n wa ọkọ ti ko ni nọmba, bẹẹ ni wọn maa n gba igba Naira (200) si ẹẹdẹgbẹta (500), lọwọ gbogbo awakọ to ba gba aaye naa kọja lalaalẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Ọgbẹni Raheem ti wọn yinbọn mọ ṣalaye pe “Nigba ti emi ati ọrẹ mi debi ti awọn Operation Burst maa n duro si yẹn, a sọ kalẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ni ki gbogbo eeyan to ba n gun ọkada kọja nibẹ maa ṣe. Ọrẹ mi n wọ ọkada rin lọ niwaju, emi n tẹlẹ e bọ lẹyin.

“Lẹẹkan naa ni mo gburoo ibọn, nigba ti mo si maa fi mọ nnkan to n ṣẹlẹ, mo ti ba ara mi nilẹẹlẹ, mo waa ri i pe emi gan-an lọta ibọn ti wọn yin ọhun ba”.

Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) yii waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati ṣewadii iṣẹlẹ yii, ki wọn si gbe igbesẹ to ba yẹ lori ẹ.

Bakan naa l’Ọba Fọlakanmi ti i ṣe Alado ti Ado-Awaye, rọ CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati fun awọn agbofinro gbogbo nipinlẹ naa ni itọsọna lori bo ṣe yẹ ki wọn maa huwa pẹlu awọn araalu ti wọn n daabo bo.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii ni Raheem ṣi n gba itọju nileewosan kan niluu Ado-Awaye, nitori ti ibọn to ba a ti fọ ọ leegun ẹsẹ.

Leave a Reply