Tinubu ti de lati London

Faith Adebọla, Eko

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti de lati irinajo rẹ sorileede United Kingdom.

Gẹgẹ bii ikede ti ọkan ninu awọn adari eto iroyin rẹ, to tun jẹ amugbagbalẹgbẹẹ eto iroyin Aarẹ Buhari, Ọgbẹni Bashir Ahmed, ṣe sọ lori ẹrọ ayelujara, ni ikanni tuita (twitter) rẹ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa yii, o ni awọn n reti Tinubu lati de kilẹ ọjọ naa too ṣu.

Ṣugbọn ni nnkan bii aago mẹfa kọja iṣẹju diẹ, awọn ololufẹ baba ti wọn fi joye Jagaban ti ilẹ Borgu ọhun gbe e sori opo tuita wọn, wọn kọ ọ bii owe ni, pe: Aṣa ti balẹ gudẹ! Eyi ni wọn fi n kede pe Tinubu ti de s’Abuja.

Ko pẹ lẹyin naa ni fidio kan gori ẹrọ ayelujara tuita awọn alatilẹyin Tinubu, wọn ṣafihan bo ṣe sọkalẹ latinu baaluu ni papakọ ofurufu nla ti Nnamdi Azikiwe, l’Abuja, o wọ jakẹẹti alawọ eeru ati ṣokoko dudu, bẹẹ lo de fila bẹntigọọ ti wọn n pe ni Panama, bo ṣe n gun akasọ baaluu naa sọkalẹ, bẹẹ lo n juwọ sawọn ti wọn ti waa duro de e lati ki i kaabọ, bẹẹ lawọn eeyan ọhun n pariwo “siti bọi, siti bọi” (city boy) iyẹn ọkan ninu inagijẹ tuntun ti wọn n pe baba naa lasiko yii.

Leave a Reply