Oluyinka Soyemi
Ikinni ‘ẹ-ku-oriire’ lawọn eeyan n ki atamatasẹ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles to n ṣe bẹbẹ ni Al-Nassr, ilẹ Saudi Arabia, Ahmed Musa, bayii pẹlu ọmọ tuntun jojolo tiyawo rẹ ṣẹṣẹ bi.
Musa funra ẹ lo kede ọrọ naa pe Juliet Ejue, iyawo keji toun fẹ, ti bimọ ọkunrin lantilanti. Eyi ni ọmọ kẹrin ti Musa bi, bẹẹ lo jẹ ọmọ keji laarin oun ati Juliet lẹyin to kọ iyawo akọkọ, Jamila, silẹ.
Oṣu karun-un, ọdun 2017, lo ṣegbeyawo pẹlu Juliet, oṣu keji, ọdun 2018, ni wọn si bimọ akọkọ.
GBS Football Academy, ilẹ Naijiria, ni Musa ti kẹkọọ nipa bọọlu lọdun 2008 si 2010, ko too lọ si awọn kilọọbu mi-in nilẹ Naijiria, Netherlands, Russia ati England, nibi to gba de Saudi Arabia.
O ti kọkọ gba bọọlu fun Flying Eagles ilẹ Naijiria ko too darapọ mọ Super Eagles, oun si ni agbabọọlu akọkọ ilẹ yii to gba ju ayo kan wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, eyi si waye nigba ti Super Eagles koju Argentina nibi idije agbaye ọdun 2014.
Bakan naa lo tun fitan balẹ gẹgẹ bii agbabọọlu Naijiria akọkọ to gba bọọlu wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ meji nibi idije agbaye, eyi si waye lọdun 2018, nigba ti Naijiria koju Iceland.