Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Irele ati Okitipupa, nileegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọmọọba Jimi Odimayọ, ti kilọ fun awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lorilẹ-ede yii lori ẹni ti wọn yoo fun ni tikẹẹti lati dije dupo gomina ninu eto idibo abẹle wọn to n bọ l’ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii.
Odimayọ toun naa wa lara awọn mẹrindinlogun to gba fọọmu idije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin yii, ni ohun to le mu ki ẹgbẹ APC fidi-rẹmi ninu eto idibo gomina to fẹẹ waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ni ki wọn fun ẹni ti yoo lo ọdun mẹrin pere ni tikẹẹti lati dije.
O ni ko ni i ṣee ṣe f’awọn eeyan ẹkun naa ki wọn fi oludije ti wọn mọ pe yoo lo ọdun mẹjọ lori aleefa silẹ, ki wọn waa lọọ dibo fun ọlọdun mẹrin pere nitori gbogbo awọn gomina ti wọn ti ṣakoso saaju lati awọn ẹkun meji yooku nipinlẹ Ondo ni wọn lo ọdun mẹjọ wọn pe lori aleefa.
Odimayọ to wa lati ilu Irele, tẹsiwaju pe awọn eeyan ẹkun naa ko ni i laju wọn silẹ ki wọn ṣi anfaani nla ti ẹgbẹ APC fun wọn lasiko yii lo lori bi wọn ṣe fun awọn eeyan to wa lati agbegbe Guusu nikan loore-ọfẹ lati dije dupo gomina ninu eto idibo to n bọ nipinlẹ Ondo.
O ni ti awọn aṣaaju ẹgbẹ awọn ba lọọ ṣe aṣiṣe fifun ọlọdun mẹrin ni tikẹẹti dipo ẹni ti yoo lo ọdun mẹjọ, afaimọ ki ẹgbẹ alatako ma lọọ gba ijọba mọ ẹgbẹ APC lọwọ ninu eto idibo gomina to n bọ ninu oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ninu ipade awọn oniroyin to pe ọhun ni Ọdunayọ naa ti fi erongba rẹ han fawọn aṣaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, atawọn araalu lati dije dupo gomina to n bọ ọhun.
Odimayọ ni gbogbo ohun to yẹ ki oludije fi kun oju oṣunwọn loun ni patapata, bẹẹ ni oun si ti ṣetan lati ba gbogbo aini awọn eeyan ipinlẹ Ondo pade lori eto aabo, ilera to peye, eto ẹkọ, ọna, atawọn nnkan amayedẹrun mi-in ti wọn ba fibo gbe oun wọle gẹgẹ bii gomina.
Awọn oludije mẹrindinlogun ni wọn ti gba fọọmu lati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ All Progressive Congress, eyi ti wọn fẹẹ ṣeto rẹ l’ogunjọ, oṣu Kẹrin yii. Ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo si ni gbogbo awọn oludije naa ti wa, ni ibamu pẹlu ilana ti ẹgbẹ APC l’Abuja ti fi lelẹ.
Ni ibamu pẹlu ofin ati ilana to de eto idibo lorilẹ-ede Naijiria, saa kan pere, iyẹn ọdun mẹrin, ni ofin faaye gba Ọnarebu Lucky Ayedatiwa to n tukọ ipinlẹ Ondo lọwọ lati lo lori aleefa to ba ri tikẹẹti gba, ti wọn si tun dibo fun un wolẹ gẹgẹ bii gomina ninu eto idibo to n bọ.
Idi ni pe, wọn ti kọkọ bura fun un lakọọkọ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja, lati pari ọdun kan ati oṣu meji ti saa keji ọga rẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu yoo pari.
Ti Ayedatiwa ba fi ri tikẹẹti ẹgbẹ gba, to si jawe olubori ninu eto idibo gomina to n bọ, ti wọn si tun bura wọle fun un gẹgẹ bii gomina, ko ni ṣee ṣe fun un lati pada dije, nitori ko ba ilana eto idibo tuntun mu ki wọn bura fun ẹni kan ju igba meji pere lọ.
Ohun ti pupọ awọn oludije ti wọn wa lati ẹkun kan naa pẹlu Gomina Ayedatiwa fi n polongo ta ko o ree ni kete to ti fi erongba rẹ han lati dije dupo gomina, orin kan naa ti ọpọ wọn si n kọ ni pe awọn ko fẹ gomina ọlọdun mẹrin lagbegbe awọn.