Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Inu ibanujẹ ati iporuru ọkan ni mọlẹbi ọmọdekunrin kan, Abdulrasheed, ẹni ọdun meji aabọ wa bayii, iwaju ile wọn ni wọn ti ji i gbe lọ lọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lagbegbe Ìdí-Àpẹ́, nijọba ibilẹ Ìlà-Oòrùn Ilọrin (East), nipinlẹ Kwara.
Gbogbo agbegbe ati ibi gbogbo lawọn mọlẹbi naa ti wa boya wọn aa ri ọmọdekunrin ti wọn ni obinrin kan lo ji i gbe ọhun.
ALAROYE gbọ pe ọmọ bibi agboole Àgbajì, niluu Ilọrin, ni ọmọ naa, to si n gbe lọdọ iya-iya rẹ ni Ìdí-Àpẹ́, ṣugbọn ti wọn ni iya kan to da aṣọ boju ji i gbe lọ.
Ọkan lara awọn mọlẹbi to ba oniroyin wa ṣọrọ sọ pe Abdulrasheed ti wọn ji gbe ọhun pẹlu ẹgbọn rẹ ni wọn dijọ jokoo niwaju ita ile wọn ko too di pe wọn ji i gbe.
O tẹsiwaju pe ẹgbọn ọmọkunrin ọhun ṣalaye pe nigba tawọn jokoo ni obinrin kan to da aṣọ boju ji aburo ohun gbe, ti obinrin ọhun jan oun ni ikuuku lọwọ ko too ji i gbe lọ.
Ọkan lara mọlẹbi to ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri sọ pe lẹyin ọsu mẹta ti baba awọn ọmọ mejeeji yii ku ni wọn ji Abdulrasheed gbe lọ, o ni koda, ile opo ni iya awọn ọmọde mejeeji yii wa.
Wọn ti waa rọ ẹnikẹni to ba ko firi Abdulrasheed ko kan si ileeṣẹ ọlọpaa to ba sun mọ wọn ju lọ, nitori pe titi di bi a ṣe n kọ iroyin yii, wọn o ti i gbọ mo ko o ọmọ naa.