Olawale Ajao, Ibadan
Idarudapọ gba gbogbo igboro ilu Ibadan kan laaarọ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2023 yii pẹlu bawọn ọdọ ilu naa ṣe fara ya nitori owo atijọ ti awọn banki, to fi mọ awọn to n taja ko gba lọwọ araalu, ti wọn ko si ri owo tuntun to yẹ ki ọn maa na gba ni banki.
Iṣoro nla lo jẹ fawọn awakọ, oni Marwa atawọn ọlọkada lati ribi ba kọja bayii nitori gbogbo oju titi nla nla to wa nigboro ilu naa ni wọn ti di pa, ti wọn si n dana sun taya kaakiri.
Lara awọn agbegbe ti wọn ti dana soju titi bẹẹ ni Mọkọla, Bodija, Apẹtẹ, Iwo-Road, Sango Ijokodo, Ẹlẹyẹle, Apẹtẹ, Ọsajin, Agodi ati bẹẹ, bẹẹ lọ.
Bi eeyan ba fẹẹ gbe nnkan irinṣẹ gba awọn agbegbe wọnyi kọja, afi ki iru awakọ tabi ọlọkada naa fi ewe tutu ha ara nnkan irinṣẹ wọn, ki awọn ero ti wọn gbe paapaa mu ewe lọwọ, bi bẹẹ kọ, niṣe ni wọn maa da oluwarẹ pada sibi to ti n bọ. Idi ti wọn ṣe n ṣeleyii ni lati fi han gbogbo aye pe ilu ko fara rọ.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ, ọkan ninu awọn ọdọ to n fẹhonu han yii, Ọlọlade Tiamiyu, sọ pe “a ṣe wahala fun iṣẹ owo, a n ṣe wahala ka too rowo ọhun gba ni banki, a o tun rowo ọhun gba, owo ta a tun waa ni lọwọ, ẹ tun sọ pe ka ma na an mọ.
“Ohun to le mu alaafia jọba ni ki wọn jẹ ka maa na awọn owo atijọ yii lọ. Bi bẹẹ kọ, ojoojumọ la o maa ṣe iwọde yii titi ti ijọba yoo fi yi ipinnu wọn pada lori ọrọ owo yii.
Ifẹonuhan awọn ọdọ wọnyi kọ ṣẹyin opin ti ijọba apapọ mu ba nina ẹgbẹrun kan Naira (₦1, 000), ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500) ati igba Naira (₦200) atijọ ti wọn yipada laipẹ yii nigbati awọn owo naa ṣi pọ lọwọ awọn eeyan rẹpẹtẹ, ti wọn ko si ri atunṣe awọn owo wọnyi gba ni banki.
Ṣaaju gbedeke ọjọ kejila, oṣu yii, ti ijọba fun awọn eeyan da lati fi ko gbogbo awọn owo atijọ ọwọ wọn pamọ si banki lawọn eeyan iba ti ṣe bẹẹ bi ko ṣe ọwọngogo owo Naira tuntun to gbalu kan yii, to jẹ pe ojoojumọ lawọn eeyan fi n to sileefowopamọ lai ri gba ju ẹgbẹrun meji si ẹgbẹrun mẹwaa Naira lọ, tabi ki wọn ma tiẹ ri nnkan kan gba rara.
Ṣugbọn bi awọn banki ati ileepo ṣe bẹrẹ si i kọ lati maa gba awọn owo atijọ wọnyi lọwọ onibaara wọn lawọn eeyan naa ti bẹrẹ si i kọ lati maa gba a lati ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde.
Diẹ lo ku ki awọn ọlọkada ati onimarwa dana sun ile-epo kan ti wọn n pe ni Keto Oil, lọna Sango si Ọjọọ, n’Ibadan, laaarọ ọjọ Aje, nitori ti awọn oṣiṣẹ ileepo naa sọ pe awọn ko gba owo atijọ.
Taarọ yii lo waa buru ju nigba ti awọn onimọto, onimarwa atọlọkada bẹrẹ si i kọ awọn owo naa sawọn ero wọn lọrun, ti ebi si n pa awọn eeyan to ni awọn owo wọnyi lọwọ, ṣugbọn ti wọn ko ri olounjẹ to maa gba a lọwọ wọn.
Nibi ti nnkan de duro bayii, ọpọlọpọ ileefowopamọ, ati eyi to lowo lọwọ o, ati eyi ti ko lowo lọwọ o, pupọ ninu wọn ni ko sanwo fun onibaara kankan bayii nitori ibẹru ikọlu to ṣee ṣe ki awọn ọdọ naa kọ lu wọn bi ede aiyede kekere kan ba ṣẹlẹ laarin awọn ero to ba to sẹnu ẹrọ wọn lati gbowo.