Awọn eeyan gboriyin fun Ọbasanjọ, nitori bo ṣe kunlẹ ki ọba Warri tuntun

Jọkẹ Amọri

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan ṣi n gboriyin fun aarẹ Naijiria nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, fun apọnle nla to fun Olu ilu Warri tuntun, Ọba Ogiame Atuwatse 111, nigba to lọọ ki i ku oriire iwuye ni aafin rẹ.

Ninu fidio ati fọto kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lo ṣafihan igba ti Ọbasanjọ wọle si aafin ọba naa, to si lọ taara sibi to gunwa si, nibi to ti kunlẹ ki i, to si fọwọ gbọn orukun ọba naa.

Ki i ṣe Olu Warri ti ko le ju ọmọọmọ baba yii lọ ni yoo kọkọ kunlẹ ki. Bakan naa ni Ọbasanjọ ṣe nigba to lọọ ki Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, nigba ti ọba naa gori itẹ. Gbalaja ni baba yii dọbalẹ ki Ọọniriṣa. Bakan naa lo si ṣe fun ọba Gbagura nigba to lọọ ki i laafin.

Gbogbo awọn ti wọn ri fọto ati fidio yii ni wọn n gboṣuba fun Ẹbọra Owu, wọn ni baba naa ko mu aṣa ati iṣe Yoruba ni kekere rara pẹlu bo ṣe n dọbalẹ lati ki awọn ọba yii gẹgẹ bii ohun ti áṣa ati iṣe Yoruba pe fun, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ẹgbẹ wọn lọjọ ori.

Wọn ni ọmọ Yoruba tootọ to bọwọ fun aṣa ati iṣe wa lai fi ti ipo to wa ati ọjọ ori rẹ ṣe ni.

Leave a Reply