Awọn eeyan ha sinu ile alaja mẹta to wo l’Ebute-Mẹta, l’Ekoo

 Faith Adebọla, Eko

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ariwo ẹkun ati igbe awọn eeyan ti wọn ko rọna jade lo bolẹ lagbegbe kan l’Ebute Mẹta, nibi ti ile alaja mẹta kan tawọn eeyan n gbe inu rẹ ti rọ lulẹ lọṣan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, yii.

Ni nnkan bii aago kan ọsan ni wọn ni ile ọhun to wa ladojukọ ileewosan Ebute-Mẹta Comprehensive Health Centre, ni Opopona Cemetery, lagbegbe Ebute-Mẹta, ṣadeede da wo, wọn lawọn eeyan rẹpẹtẹ lo n ṣe ka-ra-ka-ta labẹ rẹ latari ọgọọrọ ṣọọbu ti wọn kọ yi ile naa po nisalẹ, awọn olugbe ati ọfiisi ni wọn wa loke aja.

Obinrin alaboyun kan la ṣi gbọ pe ori ko yọ, lati ibi akitiyan tawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ọrọ pajawiri l’Ekoo, LASEMA, atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti wọn ti tete debii iṣẹlẹ naa ṣe.

Bo tilẹ jẹ pe aayan ṣi n tẹ siwaju lati doola ẹmi awọn to wa labẹ awoku ile naa, ko ti i si akọsilẹ oku eeyan kan lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ṣugbọn awọn aladuugbo tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn sọ pe ko sọgbọn kawọn eeyan ma ṣofo ẹmi latari bi ero ṣe maa n wọ latokedelẹ nile ọhun.

ALAROYE yoo maa fi to yin leti bi iṣẹlẹ naa ba ṣe n lọ si.

Leave a Reply