Faith Adebọla
Lasiko yii, iro ijo, ayọ ati itẹwọ ọpẹ lo n ṣẹlẹ lagbo awọn APC ipinlẹ Ogun, latari bi wọn ṣe kede Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti i ṣe oludije lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), p’oun lo jawe olubori sibo naa, ti yoo si bẹrẹ saa keji iṣakoso rẹ loṣu Karun-un, ọdun yii.
Irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii, ni wọn pari kika ati akojọ esi idibo gomina, eyi to waye lolu-ileeṣẹ ajọ INEC to wa ni Magbọn, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Latigba ti ikede esi idibo naa ti bẹrẹ ni Dapọ Abiọdun ti n lewaju, bo tilẹ jẹ pe gbagbaagba ni Ladipupọ Adebutu, oludije lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, n tẹle e.
Ni abarebabọ, ninu awọn ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun lo gbegba oroke ni ijọba ibilẹ mejila, nigba ti Ladi Adebutu mu ijọba ibilẹ meje.
Ẹni kẹta wọn, Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti ẹgbẹ oṣelu African Democratic Party, ADC, ẹni ti gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun n ṣatilẹyin fun, ko wọle nijọba ibilẹ kankan.
Awọn ijọba ibilẹ ti Dapọ ti wọle ni Ọdẹda, Ariwa-Ẹgbado, Guusu-Ẹgbado, Ewekoro, Ariwa-Ijẹbu, Ijẹbu-Ode, Ipokia, Ariwa-Abeokuta, Ọbafẹmi-Owode, Ado-Odo/Ọta, Ifọ ati Imẹkọ-Afọn.
Adebutu ni wọn kede pe o wọle ni Guusu-Abeokuta, Ogun Waterside, Ariwa/Ila-Oorun Ijẹbu, Ikẹnnẹ, Ila-Oorun Ijẹbu, Ariwa Rẹmọ, Ṣagamu ati Odogbolu.
Pẹlu ikede yii, Dapọ Abiọdun, to jẹ gomina kẹrin nipinlẹ Ogun latigba ti eto iṣejọba oloṣelu ti bẹrẹ pada lọdun 1999 yoo ṣe saa ọdun mẹjọ lori aleefa, gẹgẹ bii tawọn aṣaaju rẹ, Gbenga Daniel ati Ibikunle Amosun, ti ọkọọkan wọn lo saa meji, ti i ṣe ọdun mẹjọ-mẹjọ, ayafi Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, to lo saa kan ọlọdun mẹrin, iyẹn ni 1999 si 2003.