Nitori ounjẹ, iya agba yii dana sun ọmọ, iyawo atawọn ọmọọmọ rẹ mọle l’Apọnmu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ni ọrọ iya agbalagba kan, Iforiti, ṣi n jẹ ijọluju fun ọpọ eeyan. Eyi ko sẹyin bi iya naa ṣe wo sunsun, to si dana sun ara rẹ, ọmọ, iyawo ọmọ, atawọn ọmọ-ọmọ rẹ meji mọ inu ile ti wọn n gbe ni ilu Apọ́nmú, eyi to wa loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, loru ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, yii.

ALAROYE gbọ pe ọmọ iya yii, iyawo rẹ ati ọkan ninu awọn ọmọọọmọ rẹ meji ni wọn ti jade laye bayii. Ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun ni ọmọ kan ṣoṣo to ku naa si wa.

Gẹgẹ bi alaye diẹ ta a ri gbọ lati ẹnu ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, iyẹn Ọgbẹni Korede Michael, ẹni ti Ọlọrun lo lati fọ oju fereṣe, nibi to gba ko awọn eeyan naa jade kuro ninu ile to n jona ọhun, o sọ pe awọn maraarun ti wọn wa ninu ile lasiko ti iṣẹlẹ aburu naa waye ni Iforiti funra rẹ, ọmọ rẹ kan ti wọn porukọ rẹ ni Victor Ọlọrọ, Rachael Ọlọrọ, to jẹ iyawo rẹ ati awọn ọmọọmọ wọn meji, Toluwani pẹlu Blessed Ọlọrọ.

O ni ọkọ mama ọhun to ti di oloogbe lo kọle ti gbogbo wọn jọ n gbe ni Apọnmu, eyi to fa a ti wọn ko fi le ri obinrin naa le jade pẹlu awọn iwakiwa to ti hu sẹyin.

Nnkan bii aago meji oru ọjọ naa, lẹyin tawọn eeyan ti sun wọra lo ni iya agba yii ko ihá jọ, lẹyin eyi lo lọọ gbe galọọnu epo bẹntiroolu tí ọmọ rẹ da sinu jẹnẹretọ ku, n lo ba da a sara awọn ohun eelo idana ọhun, o si ṣana si i.

Ọkunrin yii ni oun lẹni akọkọ to sa jade ninu ile ọhun, ti oun si fọ oju fereṣe ile wọn, níbi ti oun gba lati ko awọn eeyan naa jade ninu ina.

Kiakia lo ni awọn ṣeto ọkọ, eyi ti wọn yoo fi gbe wọn lọ si ọsibitu ijọba to wa l’Akurẹ, ṣugbọn awọn dokita ti wọn ba lẹnu iṣẹ kọ lati gba awọn eeyan naa fun itọju, wọn ni ọwọ awọn ko le ka ọrọ itọju awọn mẹrẹẹrin ti wọn ko wa, ni wọn ba gba wọn nimọran lati tete maa ko wọn lọ si ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ.

Ọgbẹni Korede ni alẹ ọjọ ti wọn ko wọn de Ọwọ ni ọkan ninu awọn ọmọ mejeeji yii ti ku, iyẹn àbíkẹ́yìn wọn, ẹni ọdun meji aabọ ti wọn porukọ rẹ ni Blessed. Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii,  ni ọmọ iya yii ọkunrin, iyawo rẹ ati ọkan naa tun jade laye, ti ọmọ kan ṣoṣo to ku si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun nile-iwosan lọwọlọwọ.

Kayeefi to tun wa ninu iṣẹlẹ yii ni pe, ko ṣohunkohun to ṣe iya ti wọn n pe ni Iya-ajẹ ọhun bi ọrọ ina ọhun ti lágbára to, inu ile ajoku naa lo ṣi wa lati igba naa, ti ko kuro nibẹ.

Korede ni nigba ti awọn beere lọwọ mama agba yii iru ẹṣẹ ti ọmọ bibi inu rẹ ṣẹ ẹ to fi dana sun oun atawọn ẹbi rẹ, o ni ohun to fi da awọn lohun ni pe wọn ki i foun lounjẹ gidi lati jẹ.

Iya yii sọ pe oun ko lajẹẹ bi awọn eeyan kan ṣe ro, ṣugbọn oun funra oun mọ pe oun ni ika ninu jọjọ. Wọn ni obinrin naa ti figba kan jẹwọ ri pe oun loun binu pa ọmọ oun kan to wa ni yunifásítì nigba kan.

O ni Abilekọ Iforiti ti kọkọ gbiyanju lati pa ara rẹ pẹlu bo ṣe lọọ ko si kanga kan lọdun to kọja, awọn eeyan kan ti wọn fẹẹ ji pọnmi ni nnkan bii aago mẹfa idaji ni wọn ri i nibi to ha si ninu kanga ti ko le lọ si ìsàlẹ̀, bẹẹ ni ko le wa soke mọ.

Awọn araadugbo yii lo ni wọn sare sugbaa rẹ, ti wọn si wa gbogbo ọna ti wọn fi wọ ọ jade nínú kanga ọhun.

ALAROYE gbọ pe iya yii nikan lo wa ninu ile ọhun lọwọlọwọ lai jẹ jẹ tabi mu ohunkohun.

Leave a Reply