Jide Alabi
Tilu-tifọn lawọn eeyan ipinlẹ Kwara fi ya lọọ pade Dokita Bukọla Saraki, bi aṣiwaju oloselu naa ṣe tun wọlu lẹyin ọpọlọpọ oṣu to ti wa sipinlẹ ̀ọhun gbẹyin.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ni ọkunrin naa ati awọn mọlẹbi rẹ ṣe akanṣe adura fun baba wọn, Oloye Oluṣọla Saraki, lẹyin ọdun kẹjọ to ti dagbere faye.
Ile awọn Saraki to wa ni adugbo Ilọfa, ni GRA, niluu Ilọrin, ni eto adura yii ti waye. Ohun to si jọ awọn eeyan loju ni pe niṣe lawọn eeyan ilu naa tu jade bii eṣu, ti wọn si n pariwo pe, ‘o ti su wa, idẹra de.’
Yatọ si eyi, Sẹnetọ Gbemisọla Saraki, ọkan lara awọn minisita ninu ijọba Buhari naa wa nibi eto adura naa, bẹe lawọn eeyan n sọ pe igba akọkọ niyi ti oun ati ẹgbọn rẹ yoo pade, lẹyin to ti ba awọn ọta ẹgbọn ẹ ninu oṣelu, iyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ APC lọ.
Nibi ayẹyẹ fidau ọhun, pitimu bayii lawọn ero pe, paapaa awọn ti wọn jẹ ololufẹẹ awọn Saraki. Ni papakọ ofurufu ilu Ilọrin ni wọn ti lọọ pade ẹ, ti wọn si sin in titi to fi dele wọn, nibi ti eto ọhun ti waye. Awọn aafaa agba lo ṣe waasi lọjọ naa, ohun ti wọn si fi koko ọrọ wọn le ni pe, gbogbo abiyamọ pata lo gbọdọ tọju ọmọ wọn daadaa, ki wọn le ni ẹyinwa-ọla to dara.
Imaamu ilu Ilọrin, Shehu Mohammed Bashir Solihu, lo ṣaaju wọn nibi eto adura ọhun. Bẹẹ lawọn agba aafaa mi-in n’Ilọrin naa tun kun un, ninu wọn ni Shehu Sulaimon Dan Borno, Shehu Saanu Shehu ati Imaamu AbdulRazaq Aduagba.
Shehu Sulyman Dan Borno dupẹ lọwọ Dokita Bukọla Saraki ati aburo ẹ, Gbemisọla Saraki, bi awọn mejeeji ṣe jọ peju-pesẹ sibi adura naa. O ni niwọn igba ti wọn ba ti gba ara wọn mu, ti wọn si n lo ifẹ pẹlu ara wọn, ko sẹni kan bayii ti yoo mọ asiri Ilọrin.
Lara awọn eeyan pataki to wa nibi adura pataki yii ni, Sẹnetọ Rafiu Ibrahim; alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Enjinnia Kọla Shittu; Alhaji Abubakar Kawu Baraje, olori ile-igbimọ aṣofin nipinlẹ Kwara tẹlẹ, Dokita Ali Ahmad atawọn eeyan pataki mi-in lawujọ.