Aderohunmu Kazeem
Pelu ibinu lawọn eeyan fi n ṣepe le ọmọ Alaaji Wasiu Ayinde, Arabinrin Damilọla Marshal, lórí bo ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn eeyan to n ṣatilẹyin fun Sunday Igboho.
Arabinrin to pe ara ẹ ni akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ ofin yii sọ pe ki í ṣe ohun to ba ojú mu b’awọn eeyan ṣe sọ Igboho di olokiki lojiji, ti awọn oniroyin kan n pè é ni ajijagbara iran Yoruba, ti awọn kan lati ilẹ okeere si tun n da owo bayii, ti wọn láwọn fẹẹ fi ra awọn bọọsi ti yoo maa lo fun iṣẹ ijijagbara to n ṣe.
Damilọla fi kun un pe gbogbo ọmọ Yorùbá ni wọn ṣì gbọdọ rántí ogun Ifẹ ati Mọdakẹkẹ daadaa, ohun toju awọn eeyan ri, ati pe Sunday Igboho yii kan naa kopa ninu ogun ọ̀hún, kò sí yẹ ki ọmọ Yorùbá to fẹẹ alaafia, to lodi si wahala, fara mọ ohun ti Sunday Igboho n ṣe kiri yii.
Ọmọbinrin yii ni niṣẹ lo yẹ kí ìjọba fọwọ ṣikun mu ẹnikẹni tó bá ti lọwọ sí ariwo ogun ti ọkunrin yii n pa. O ni ọmọ Yorùbá gidi loun, bẹẹ loun yóò máa rí iran Hausa ati Ibo gẹgẹ bii mọlẹbi oun.
Ọrọ ti Dami Marshal, ọmọ gbajumọ olorin fuji nní Alaaji Wasiu Ayinde, sọ niyẹn ti awọn eeyan fi kọ lu u, ti wọn fi n ṣepe fún un.
Wọn ni ko si ọmọ Yorùbá gidi kan tó yẹ kó sọ ohun ti obinrin yii sọ sí Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, nitori ija gbogbo Yorùbá lo n ja.
Bakan naa láwọn eeyan n sọ pé ẹnikẹni tó bá lòdì sí Sunday Igboho, ọta Yoruba ni, bẹẹ epe lo yẹ iru wọn.
Awọn mi-in ni epe lo maa pa apẹlu ọrọ buruku to n sọ jade lẹnu naa. Epe oriṣiiriṣii lawọn eeyan si n gbe e ṣẹ fun ọrọ ti wọn ka si ọrọ agọ to sọ ọhun.
Bẹ o ba gbagbe, Damilọla yii kan na lo sọrọ si aọn ti wọn n ṣe iwọde lodi si awọn SARS ninu oṣu kẹwaa ọdun to kọja. Oriṣiiriṣii orukọ lo pe awọn eeyan naa to ni wọn di oun lọwọ lati lọ si ibi iṣẹ oun pelu iwọde ti wọn n ṣe.
Ọrọ naa ko dun mọ awọn eeyan ninu nigba naa, niṣe ni wọn si n bu u lori ikanni rẹ lasiko naa.