Awọn eeyan sọrọ si Fathia Balogun, nitori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ to kopa ninu ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Tẹni to de la ri ni oko ọrọ to n bọ sori Fathia Balogun lasiko yii, o daju pe ti ẹnikọọkan ninu awọn oṣere to kopa ninu sinima Yọmi Fabiyi, Ọkọ Iyabọ’, yoo ṣi ba wọn pẹlu ọrọ buruku. Ṣugbọn lọwọ yii, Fathia lojo ọrọ buruku ṣi n rọ lori rẹ na.

Ohun to n bi ọpọ eeyan to n sọrọ si oṣere yii ninu ni pe pẹlu bo ṣe jẹ agba oṣere to lorukọ to, wọn lo yẹ ko mọ iru ere ti yoo ti kopa. Awọn ololufẹ sinima to ti wo fiimu naa lori ayelujara sọ pe ko ba ma jẹ Fathia, wọn lo yẹ ko loye ju bẹẹ lọ.

Awọn mi-in tiẹ sọ pe nitori ija buruku to wa laarin Fathia Balogun ati Iyabọ Ojo lo jẹ ki oṣere yii gba lati kopa ninu ere ti wọn pe ni ‘Ọkọ Iyabọ’ yii. Wọn ni nitori bi Iyabọ Ojo ṣe maa n fi Fathia wọlẹ lo jẹ kobinrin yii gba lati kopa ninu sinima ọtẹ, wọn lo fẹẹ fi pẹgan Iyabọ ni.

Ohun ti wọn ni ‘Ọkọ Iyabọ’ da le lori ni pe ko sohun to buru bi ọmọdebinrin ba n yan agbalagba lọrẹẹ, latigba ti ere Yọmi yii si ti gori afẹfẹ ni ida mẹsan-an ninu mẹwaa awọn to wo o ti n koro oju si i.

Bi wọn ṣe n pe Yọmi to kọ ọ lorukọ buruku lawọn mi-in ṣepe fawọn oṣere to ba a kopa nibẹ.

Iṣẹ ọhun ko si ki i ṣe kekere rara o, nitori awọn agba oṣere pọ nibẹ. Madam Ṣajẹ, Ogogo, Ẹlẹṣhọ, Lọla Idijẹ-ẹ, Ọlọfaana, Ajala Jalingo atawọn oṣere nla-nla lo wa ninu ‘Ọkọ Iyabọ’. O jọ pe ori Fathia lawọn aye ti fẹẹ bẹrẹ ibawi naa ni wọn ṣe n juko ọrọ lu obinrin to ti le laaadọta ọdun naa bayii.

Ẹnikan torukọ ẹ n jẹ ‘One Scents by Halar’ n ṣepe fun Fathia ni tiẹ ni, epe ti ko ṣee kọ soju iwe iroyin lo bu jo Fathia, bẹẹ lo ni oun ko mọ pe beeyan kan ba kọ iru ere ‘Ọkọ Iyabọ’ yii, to si ni ki Fathia waa kopa nibẹ, oun ko mọ pe iyawo Saheed Balogun tẹlẹ naa yoo gba iru ere bẹẹ. O ni Fathia ja oun kulẹ gan-an ni.

Ẹni yii ko ti i dakẹ, One Scent sọ pe bi Fathia ko ba lẹkọọ ọmọluabi ti yoo fi kọ iru iṣẹ bẹẹ silẹ, ṣe ko tun ni ẹkọ ofin bo ti wu ko kere mọ ni, pe eeyan ki i fi itan igbesi aye ẹlọmi-in to jẹ ẹdun ọkan rẹ ṣere. To bẹẹ to jẹ wọn tun n lo orukọ awọn ẹni to ṣẹlẹ si naa bi wọn ṣe n jẹ ẹ loju aye.  Ẹni to binu si Fathia yii ni ọrọ rẹ ko jọ oun loju, ohun to jẹ ki Rẹmi Surutu gba a leti nita gbangba niyẹn, to kọ ọ lẹkọọ to yẹ ko ni ṣugbọn ti ko ni.

Ẹlomi-in to tun bu Fathia loju opo ni Mafuzah, o ni ṣebi agba ki i wa lọja kori ọmọ tuntun wọ ni Yoruba wi, ewo waa ni ti Fathia ti agba tiẹ ko wulo. O ni Agbaya ni Fathia, ẹranko si ni pẹlu.

Bi ọrọ yii ṣe fẹju toto yii, AKEDE AGBAYE ba Yọmi Fabiyi to kọ ere to da wahala silẹ naa sọrọ lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu keje yii, lati gbọ ti ẹnu rẹ.

Ọkunrin naa ni oun ko ni alaye kankan lati ṣe mọ, nitori oun ti fi ero ọkan oun sori ẹka ayelujara nipa fiimu naa.

Ohun ti fi sita naa lo ti ṣalaye pe oun lẹtọọ lati kọ itan to ba wu oun, o ni eebu ati ọrọ abuku lati ẹnu awọn ẹlẹgbẹ oun pẹlu ara ilu ko ni nnkan i ṣe pẹlu ẹtọ oun lati gbe iṣẹ ọpọlọ jade.

Yọmi sọ pe wọn ko fi ofin de iṣẹ oun, ‘Ọkọ Iyabọ’ lati ma jade. O ni awọn alaṣẹ kan fi mọ lori ayelujara ni, ko le baa din ariwo awọn eeyan to n naka abuku si fiimu naa ku.

‘’Mo fa gbogbo yin le ẹri ọkan yin ati Ọlọrun lọwọ. Ko si ohun tẹ ẹ le ṣe to le fa mi sẹyin.’ Bẹẹ ni Yọmi Fabiyi kọ ọ soju opo Instagraamu rẹ.

O fi kun un pe to ba ya, ileeṣẹ to n ri si sinima to le jade yoo faaye silẹ fun ‘Ọkọ Iyabọ’ lati di tita lori igba, awọn yoo ṣe e si DVD. Nigba naa ni kaluku yoo ri i pe ohun to ṣẹlẹ ko ju pe awọn oṣẹre meji, Yọmi ati Iyabọ, n ja lori ọrọ kan, ọtọọtọ si loju ti kaluku wọn fi wo o.

Boya lohun ti Yọmi wi yii ta leti awọn eeyan ṣa, nitori lẹyin to kọ ọrọ tiẹ sita lawọn eeyan nawọ gan Fathia yii, ti wọn n bu u bii ẹni layin.

Koda, awọn TAMPAN gan-an ti ranṣẹ pe Yọmi Fabiyi, wọn ni ko foju kan awọn lọjọ kọkanla, oṣu keje yii, lati waa ṣalaye ara ẹ nipa sinima ‘Ọkọ Iyabọ’, nitori iṣẹ rẹ yii ti n ko eeri igi yi obi awọn lara, awọn eeyan tun ti n sọrọ odi si TAMPAN, bẹẹ, ẹru kan ni i mu ni bugba ẹru lọrọ yii. Wọn ni ki Yọmi Fabiyi waa foju kan igbimọ, ko waa rojọ ẹnu rẹ boya yoo jare.

 

Leave a Reply