Florẹnce Babaṣọla, Osogbo
Boya nitori bi awọn ara ipinle Eko ṣe ya bo ile ẹru tijọba ko ounjẹ ti wọn gba lasiko korona si, ti wọn si pin gbogbo re mọra wọn lọwọ lo fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun naa nigboya ti wọn fi ṣe beẹ. Niṣe ni awọn eeyan naa kọ lu ile ẹru ti ijọba Ọsun ko ounjẹ ti wọn ri gba lasiko korona si, ti wọn si ja ilẹkun ibe. Niṣe ni onikaluku bẹrẹ si ko ohun ti ọwọ rẹ ba.
Niṣe ni awọn mi-in gbe ọkada wa, ti wọn si ko ẹru sori rẹ bamu. Awọn ti ko ni ọkada n fori ru tiwọn, onikaluku si n ko ohun to le ko ninu ile ẹru ọhun.
Ko sẹni to mọ ẹni to ta awọn eeyan naa lolobo ti wọn fi mọ pe wọn tọju ounjẹ to yẹ ki wọn fun araalu lasiko korona sibẹ, ti wọn fi ya lọ sibẹ bii esu.
Tikobasepe oloriburuku ,awon tiwonmasofo tomotomo won,awon tiwon o ni jeyan tiwon mafiku ijobawani awon ijoba naijiria, ounje toye kawa mekunnu maje won sise bose wuwon .lagbara olohun awon omowon majiya kiwon toku ni afitikobajepe olohun lodawa na ko loseku.
Eje Kia fi oju Inu wo, won fun awa ara ilu ni ohunje lasiko korona pe kia pin ebi sin npawa nigba yen won o pin, kise ijoba loni awon ounje yii oo, awon olowo ilu ni won gbe fun wa , won si tun gbe pamo se won fe ki ebi pawa ku ni ati wipe kini ijoba fe fi awon ounje naa se tiwon fi gbe pamo won fi iya je wa nio egba waa kiesi ran wa lowo iya nje was ooooo9