Eeyan mẹwaa ku nibi ijamba mọto l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ko din lawọn arinrinajo bii mẹwaa to ku sinu ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Olufoam, loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYYE gbọ pe awakọ ajagbe kan ti nọmba rẹ jẹ KJA 14  XW lo lọọ fori sọ ọkọ bọọsi elero mejidinlogun kan nibi to ti n gbiyanju ati pẹ ọwọ fun ọlọkada to deedee jana mọ ọn lẹnu.

Loju ẹsẹ ni mẹwaa ninu awọn ero to wa ninu ọkọ boosi ọhun ti ku, nigba tawọn yooku fara pa yannayanna.

Awọn to fara pa ninu ijamba ọhun lawọn ẹsọ aabo oju popo kọkọ gbiyanju ati ko lọ si ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ fun itọju, lẹyin eyi ni wọn pada waa ko oku awọn to padanu ẹmi wọn lọ si mọṣuari ọsibitu yii kan naa.

Leave a Reply