Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo ounjẹ gbigbẹ tijọba apapọ ko pamọ si agbegbe Ọṣun Ankara, ni Irojo, niluu Ileṣa, lawọn araalu tinu n bi ti ko tan bayii.
Silo yii ni wọn kọ lasiko iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan. O wa kaakiri orileede yii. Ṣe nijọba apapọ maa n ko ounjẹ sibẹ lasiko ojo, to ba ti di asiko ẹẹrun ni wọn maa n ta a.
Nigba to di pe awọn eeyan agbegbe Ẹdẹ ri ounjẹ Corvid 19 tijọba ko pamọ siluu wọn lonikaluku naa bẹrẹ si i wa gbogbo ibi ti ounjẹ ijọba le wa niluu tiwọn naa.
Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Honarebu Timothy Owoẹyẹ, to wa lati agbegbe naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.