Awọn ẹlẹsin abalaye fẹẹ ran Makinde lọwọ lori ipenija eto aabo

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ Ọyọ, awọn ẹlẹsin ibilẹ ti ṣetan lati ran ijọba lọwọ pẹlu ẹbọ riru, etutu pẹlu agbara oogun abẹnu gọngọ.

 
Ipinnu ọhun jẹ yọ ninu ipade ti awọn ẹlẹsin ibilẹ ṣe pẹlu ijọba Gomina Ṣeyi Makinde l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
 
Nileeṣẹ eto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ to wa ninu ọgba sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ nipade ọhun ti waye.
 
Nigba to n fẹmi imoore han si atilẹyin awọn ẹlẹsin abalaye fun ijọba Gomina Makinde, Kọmiṣanna feto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ ni ipinlẹ naa, Ọnarebu Wasiu Ọlatubọsun, fi awọn olujọsin naa lọkan balẹ pe ijọba yoo ya ọjọ kan silẹ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fi maa ṣami ayajọ ẹṣin ibilẹ lọdọọdun gẹgẹ bii adehun ti oun ti ṣe fun wọn lati ibẹrẹ iṣejọba oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ri i pe ijọba ya ọjọ kan sọtọ fun awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ yii. Iru nnkan bayii ki i ṣe ohun to maa n ya kiakia ni, a ni lati gbe e gbọna ofin, kawọn aṣofin yiri ẹ wo ki wọn si sọ ọ dofin.
“Awọn baba wa ni ọna ti wọn n gba bori ipenija eto laye atijọ. Lara awọn nnkan ti awọn baba wa ti lo ṣaaju yẹn, awa naa le ṣamulo awọn kan ninu ẹ lati ṣẹgun ipenija eto aabo taa doju kọ lasiko yii.”

Leave a Reply