Awọn eleyii ji Fẹlicia gbe l’Ajuwọn, orileede Bẹnẹ ni wọn fẹẹ sọda si ti wọn fi mu ọn  

Gbenga Amos, Ogun

 Ibi ti wọn ti n tọju ọmọbinrin ọmọọdun mẹrindinlogun kan, Felicia Okechukwu, ki laakaye ẹ le pada bọ sipo lo wa bayii, latari bawọn afurasi ajinigbe ti wọn n fi ọmọde ṣowo ẹru, Kazeem Moye, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ati Kukọyi Moye, ẹni ogun ọdun, ṣe ji ọmọbinrin naa gbe, bi ko ba si jẹ ti ọkada Bajaj wọn to yọnu ni, diẹ lo ku ki wọn raaye sọda sorileede Benin, n laṣiiri fi tu, tọwọ si ba wọn ni Iyana Agọ.

Alukoro ajọ So-Safe nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Moruf Yusuf, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii.

Yusuf ni loore-koore lawọn ẹṣọ alaabo So-Safe maa n lọ yika lati ṣakiyesi awọn oniṣẹẹbi, patiroolu naa ni wọn n ṣe lọwọ ti wọn fi kẹẹfin Kazeem ati Kukọyi pẹlu ọmọbinrin ti wọn fa lọwọ bii ẹran ni nnkan bii aago mẹta irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Keji yii.

O lara fu awọn So-Safe ti wọn ri wọn, ni wọn ba lọọ ba wọn lati beere ibi ti wọn ti n bọ ati ibi ti wọn n lọ, amọ alaye tawọn afurasi naa ṣe ko jọra, idahun wọn ko si ja geere.

Wọn tun beere lọwọ ọmọbinrin naa bi tiẹ ṣe jẹ, o loun o mọ wọn ri, o ni agbegbe Ajuwọn si Akute, loun n gbe, nijọba ibilẹ Ifọ, nipinlẹ Ogun. O loun ko mọgba ti wọn mu oun de agbegbe Iyana Agọ, nitosi Idiroko, nibi ti wọn ti fẹẹ sọda sorileede Bẹnẹ.

Eyi lo mu kawọn agbofinro naa fi pampẹ ofin gbe wọn.

Nigba ti wọn ṣewadii, aṣiri tu pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa awọn afurasi ọdaran mejeeji yii tẹlẹ, wọn lo pẹ tawọn eeyan ti n mu ẹsun wọn wa lori aṣa jiji ọmọọlọmọ gbe lọọ fi ṣẹru.

Wọn ni afaimọ ni wọn ko ti ṣepalara kan fọmọbinrin naa tori laakaye ẹ ko jipepe mọ.

Ṣa, loju-ẹsẹ ni wọn ti wọn awọn afurasi naa sọkọ, pẹlu ọkada ti wọn sọ di irinṣẹ ijinigbe, wọn lọọ fa wọn le awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ajuwọn, fun iwadii to lọọrin, lẹyin eyi ni wọn yoo foju bale-ẹjọ

Bẹẹ ni wọn ti ṣeto fun Felicia lati ri itọju iwosan gba.

Leave a Reply