Awọn eleyii ji jiipu pasitọ ni Ṣiun, wọn lọọ ta a si Mọkwa, nipinlẹ Niger

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Lọjọ kẹsan-an, oṣu keji, to ṣẹṣẹ pari yii, ikọ adigunjale ẹlẹni marun-un ya bo ile pasitọ kan, Godwin Ọjẹrinde, ni Ṣiun, ipinlẹ Ogun, wọn si ji ọkọ jiipu Pathfinder ti pasitọ n lo lọ, wọn ta a si Ogere. Ṣugbọn nigba tawọn ọlọpaa yoo ri mọto naa, Mọkwa, nipinlẹ Niger, ni wọn ti ri i.

Meji ninu ikọ adigunjale naa lawọn ọlọpaa ri mu, orukọ wọn ni Oshilaru Biọdun ati Tolulọpẹ Oluwafẹmi, to jẹ obinrin.

Ohun ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ lori iṣẹlẹ yii ni pe pẹlu ibọn atawọn irinṣẹ to le ṣeeyan nijamba ni ikọ adigunjale yii wọ ile Pasitọ Ọjẹrinde ni nnkan bii aago mẹta oru kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ọjọ naa.

O ni wọn tilẹkun mọ pasitọ atawọn ẹbi ẹ, wọn ko wọn ni papamọra, wọn si gbe jiipu ti nọmba ẹ jẹ WDE-38-MM sa lọ. Yatọ si mọto yii, wọn tun ji foonu meji ti i ṣe Samsung A20 ati Infinix hot note.

Ìwádìí ati itọpinpin awọn ọlọpaa lẹyin ifisun pasitọ lo jẹ ki wọn ri Biọdun ati Tolulọpẹ yii mu, awọn naa ni wọn si jẹwọ pe marun-un lawọn, àwọn mẹta yooku ti na papa bora.

Wọn ṣalaye pe Ogere lawọn ta mọto naa si, ṣugbọn o ti wa lọna ilẹ Hausa.  Nigba tawọn ọlọpaa yoo si ri mọto naa loootọ, Mọkwa ni wọn ti ri i, nipinlẹ Niger. Awọn tọwọ ba yii ti wa lẹka iwadii, iṣẹ si ti n lọ lati mu awọn mẹta to sa lọ naa gẹgẹ bi aṣẹ CP Edward Ajogun.

 

Leave a Reply