Awọn eleyii n fẹwọn ṣere, irin reluwee ni wọn lọọ ji ko n’Ijọra

Faith Adebọla

Ibi tọkanjuwa ẹni ba so si leeyan ti n ka a loootọ, ṣugbọn ni bebe ẹwọn Fọlọrunṣọ Adeṣina ati Victor Akpan ti lọọ ka tiwọn o, irin reluwee tijọba ko jọ lawọn lọọ ji ko, wọn fẹẹ maa sa lọ lawọn agbofinro mu wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti ninu atẹjade kan sọ pe nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde to lọ yii, lọwọ ba awọn afurasi mejeeji, ẹni ọdun mọkanlelogun ni wọn pe Victor, oun ni wọn lo wa mọto ti wọn gbe waa jale. Ojule kẹrindinlogoji, Opopona Biefield, l’Apapa, ni wọn ni Fọlọrunṣọ n gbe ni tiẹ, wọn o sọ pato ọjọ-ori ẹ.

Awọn kan ti wọn fura si wọn bi wọn ṣe n ko awọn irin ọhun sinu mọto wọn ni wọn woye pe awọn araabi yii ki i ṣe oṣiṣẹ reluwee, awọn o si ri ami pe wọn gbawe aṣẹ lati ko nnkan ti wọn n ko yii, ni wọn ba tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago, oju-ẹsẹ si lawọn agbofinro lati Eria E, ni Festac, ti kan wọn lara.

Nigba ti wọn bi wọn leere pe pe bawo ni ti irin reluwee ti wọn n ko sinu mọto ṣe jẹ, wọn ni Victor loun o mọ nnkan kan nipa ẹ ni toun, Fọlọrunṣọ lo haaya oun pe koun waa ba oun fi mọto ko irin lọ sibi kan ni Apapa. Wọn ni Fọlọrunṣọ ko fesi kan ju pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn fori ji oun lọ, n lawọn ọlọpaa ba ko ṣẹkẹṣẹkẹ si wọn lọwọ, wọn si fi pampẹ ofin gbe wọn.

Wọn ni kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti gbọ siṣẹlẹ ọhun, o si ti paṣẹ pe ki wọn fawọn afurasi naa ṣọwọ si Panti, ni Yaba, nibi tawọn ọtẹlẹmuyẹ aa ti ṣe iwadii to gbopọn nipa ẹ, ki wọn too foju wọn ba ile-ẹjọ pẹlu ẹsibiiti mọto wọn.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: