Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Nnkan o ṣẹnuure fun ikọ awọn ajinigbe kan ti wọn ji iya atọmọ gbe lagbegbe Alápá, nijọba ibilẹ Asà, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pẹlu bi wọn ṣe pa ọkan ninu wọn, ti wọn si tun fipa gba iya atọmọ ti wọn ji gbe ọhun silẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ni agbegbe Alápá, nijọba ibilẹ Asà, nipinlẹ Kwara, ni awọn ajinigbe yii ti ji iya atọmọ ẹ gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Ni kete ti wọn ji awọn eeyan naa gbe ni awọn ẹṣọ alaabo fijilante ti gba ya awọn agbebọn naa, ti wọn si tọpasẹ wọn lọ.
Alaga ẹgbẹ fijilante ni Kwara, Ọgbẹni Saka Ibrahim, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE pe ninu igbo kan ti wọn n pe ni Àjùwọ̀n, Tèmídire, ni awọn ajinigbe naa ati fijilante ti doju ibọn kọra wọn, ti gbogbo agbegbe na si da bii oju ogun pẹ̀u bi iro ibọn ṣe ro lakọ-lakọ lasiko ti wọn fẹ doola iya atọmọ rẹ tawọn eeyan naa ji gbe. Wọn mu agbebọn kan balẹ, wọn doola awọn ti wọn ji gbe, ṣugbọn fijilante meji lo fara gbọta, ti ọn si wa wa nileewosan ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE, o ni loootọ ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Alápá, nijọba ibilẹ Asà, nibi ti awọn ajinigbe naa ti ji iya atọmọ gbe, sugbọn ni igbo Àjùwọ̀n, ni ajinigbe yii atawọn fijilante ti doju ibọn kọra wọn, ti wọn si mu agbebọn kan balẹ.
Ajayi ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.