Awọn Fulani agbebọn ya wọ Agọ Igbira, l’Ọsun, wọn ji gende-kunrin kan lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn agbebọn ti wọn fura si bii Fulani ti ji ọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Mohammed Jubril, gbe lọ ni Agọ Igbira, to wa niluu Ila, nipinlẹ Ọṣun.

Ẹnikan to jẹ olugbe abule naa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mejila oru Ọjọruu, Wẹsidee, iyẹn ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn agbebọn bii mẹjọ naa de.

O ni ko too di pe wọn ri Mohammed gbe, awọn olugbe agbegbe naa ti kọkọ doju ibọn kọ wọn, ti ẹni kan, Hassan Jubril, si fara pa.

O fi kun ọrọ rẹ pe bi wọn ṣe gbe Mohammed ni wọn mori le ọna igbo kan to jẹ aala to wa laarin ipinlẹ Ọṣun ati Kwara.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe Ṣeriki Fulani niluu naa, Mohammed Kajibo, lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

Ọpalọla ni ọkunrin naa lo jẹ ko di mimọ pe laarin aago mọkanla alẹ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, si aago mejila aarọ ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, lawọn Fulani agbebọn naa fi ṣiṣẹ ni Agọ Fulani ọhun.

O ni pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ alaabo araalu (Civilian Joint Taskforce), wọn ri ọta ibọn mẹta ninu igbo to wa lagbegbe naa.

Ọpalọla sọ siwaju pe awọn ikọ alaabo yii ti wa ninu igbo kaakiri bayii lati ṣawari Mohammed, ati lati fi pampẹ ofin mu awọn agbebọn naa.

Leave a Reply