Florence Babaṣọla
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe awọn Fulani darandaran ti ji awọn arinrin-ajo meje gbe loju-ọna Ileṣa si Akurẹ.
Nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, la gbọ pe wọn ji awọn eeyan naa gbe laarin ilu Iwaraja si Ẹrinmọ, wọn si ko wọn lọ sinu igbo kan ninu ilu Iwaraja.
A gbọ pe awọn eeyan naa ti wọn n kọja lati Akurẹ lọ siluu Ileṣa ni awọn ajinigbe fi mẹta silẹ lara wọn laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ti wọn si sọ fun wọn pe ki wọn lọọ wa owo wa lati gba awọn mẹrin to ku silẹ.
Alakooso ikọ OPC nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Deji Aladeṣawẹ, sọ fawọn oniroyin pe awọn ajinigbe yii yọnda obinrin meji ati ọkunrin kan laaarọ ọjọ Iṣẹgun, awọn mẹta ọhun ni wọn si sọ pe Fulani darandaran lawọn ajinigbe naa.
Aladeṣawẹ ṣalaye pe awọn OPC pẹlu awọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wa ninu igbo naa lati tu awọn eeyan ọhun silẹ.