Faith Adebọla
Awọn afẹmiṣofo ẹda kan ti wọn fura pe Fulani darandaran ni wọn, ti da ẹmi eeyan mejidinlogun legbodo, niṣe ni wọn ya bo wọn lọjọ ọja tawọn eeyan naa n ṣe ka-ra-ka-ta wọn lọwọ, wọn yinbọn pa wọn, wọn si ṣe ọpọ eeyan mi-in leṣe.
Ileto mẹrin ọtọọtọ lawọn apanijaye ẹda naa ti ṣọṣẹ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nijọba ibilẹ Guma, ipinlẹ Benue.
Ọjọ naa bọ si ọjọ ti wọn n na awọn ọja adugbo kan lagbegbe ọhun.
Ba a ṣe gbọ, awọn apaayan naa kọkọ paayan mẹwaa lọja Abule Ukohol, wọn ni niṣe ni wọn kan n yinbọn gbau gbau lu ẹnikẹni ti wọn ba foju ri, atọmọde atagba ni wọn pa, obinrin lo si pọ ju ninu wọn.
Lati Ukohol ni wọn ti lọ si awọn abule mẹta to wa nitosi, eeyan mẹjọ ni wọn tun mu balẹ nibẹ.
Ọkan ninu awọn to kagbako iṣẹlẹ aburu yii, Ọgbẹni Ikpuku Jembe, lo jẹ olori awọn ọdọ ilu Ortese.
Alaga ijọba ibilẹ Guma, Ọgbẹni Mike Ubah, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o leeyan mejidinlogun lawọn ri oku wọn ṣa jọ, o lohun to buru ju lọ ni bawọn apaayan naa ko ṣe ṣaanu awọn ọmọde, wọn yinbọn pa awọn majeṣin tọjọ ori wọn ko ju ọdun meji pere lọ. O nigba tawọn olubi ẹda naa n pada sinu igbo ti wọn ti wa ni wọn ya lawọn ileto mẹta to wa lọna ti wọn n gba pada, ti wọn si n pa ẹnikẹni ti ba wọn ri.
Mike ni: “Ohun tawọn eeyan yii fẹẹ ṣe ni ki wọn pa awọn olugbe agbegbe yii laya, kawọn araalu le fi ibugbe ati oko wọn silẹ, ki wọn le pada waa maa da maaluu wọn kiri oko ati abule awọn ẹni ẹlẹni.
Aṣọ dudu ni wọn wọ, wọn o si da ibi kankan si, gbogbo wọọdu mẹwaa to wa nijọba ibilẹ yii ni ọrọ yii kan bayii.” Gẹgẹ bo ṣe wi.