Awọn Fulani ji olori ilu Imọpẹ gbe n’Ijẹbu-Igbo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari olori ilu Imọpẹ, nitosi Ijẹbu Oru, ti awọn agbebọn ji gbe lọsan-an ọjọ Satide, ogunjọ, oṣu kẹta yii, iyẹn Oloye Tajudeen Ọmọtayọ, (Alademẹta) awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ iṣẹ lori bi wọn yoo ṣe ri i gba pada lalaafia.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ f’ALAROYE pe wọn ji TKO Ọmọtayọ, bi wọn tun ṣe maa n pe e, gbe laaarọ ọjọ Satide yii, ṣugbọn awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori bawọn yoo ṣẹ ri i gba pada lalaafia ara.

Ohun ti a gbọ ni pe Ijẹbu-Ode ni ọkunrin naa lọ, nnkan bii aago mọkanla aarọ ni wọn lo jade nile pẹlu mọto jiipu rẹ ti nọmba ẹ jẹ W 3J9 Ogun.

Nigba to n pada bọ, ni nnkan bii aago mẹta ọsan, to de ibi kan ti wọn n pe ni Oke-ẹri ni wọn ni awọn kan ti wọn fura si pe Fulani ni wọn, yọ si ọkunrin naa tibọntibọn ti wọn si gbe e lọ.

Wọn ko fọwọ kan jiipu ẹ, wọn fi mọto naa silẹ sibẹ ni.

Imọpẹ ko ti i ni ọba, iyẹn ni a ko ṣe le fidi ẹ mulẹ pe ọba ni TKO bawọn ẹka iroyin mi-in ṣe n gbe e.

Ọkunrin ti wọn ni oun ni aarẹ ẹgbẹ Ijẹbu-Igbo Club yii wa lati idile ọba mẹta ni, iyẹn ni wọn ṣe n pe e ni Alademẹta. Oun naa la gbọ pe o n ṣe kokaari ilu Imọpẹ to si da bii olori ibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti fi i jọba.

Yatọ sawọn ọlọpaa to n ṣakitiyan lati ri TKO, awọn fijilante pẹlu awọn ọlọdẹ adugbo naa ko sun


mọ bayii, wọn n gbiyanju lati ri olori ilu Imọpẹ, ilu to wa ni Ariwa Ijẹbu, nijọba ibilẹ Ijẹbu-Igbo, nipinlẹ Ogun

Leave a Reply