Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
ALAROYE pe Kabiyesi Ọba ilu Iwoye-Ketu, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn lori ọrọ yii, Ọba Joel Ademọla Alaye Arẹmu, ṣalaye pe Ọladele ko de awọn ilu Yewa yii ko mọ bo ṣe n lọ ko too maa sọ pe awọn ọmọ Benin lo n pada siluu wọn.
Kabiyesi sọ pe ọmọ ilu ni Ọladele, ṣugbọn nigba ti wọn ti yan an sipo ni ko ti sọrọ sibi tọrọ wa mọ.
‘’Bi ẹ ba de ọdọ wa yii bayii, ko sẹni kan to n lọ soko mọ, ibẹru awọn Fulani ko jẹ. Ẹ wo obinrin kan ti wọn n pe ni Elisa ti wọn pa lọjọ Mọnde yẹn, ọmọbinrin yẹn lọọ pọnmi ni,ko sẹni to mọ pe Fulani ti pa a sodo, nigba ti wọn reti ẹ titi nile ti wọn ko ri i ni wọn wa a lọ sodo, nibẹ ni wọn ti ba oku ẹ ti wọn ti ṣa a pa. Agbẹ lọkọ Elisa naa, wọn n dako lọdọ wa nibi ni.
‘’Odo to lọ yẹn jinna, nitori a ni iṣoro omi nibi dẹ ni. Odo to mọ to ṣee mu lo fẹẹ lọọ pọn, awọn Fulani yii naa ko dẹ yee ko maaluu wọnu omi ọhun, wọn ti ba a jẹ fun wa. Odo yẹn lo lọ to ti bọ sọwọ awọn Fulani to ṣa a pa.
‘’Igba wo lawọn eeyan ko tun ni i sa lọ si Benin pẹlu bi wọn ṣe n pa wa yii. Ajitoni ni wa bayii o, a o mọ ọjọ ta a maa sun ta a o ni i ji i mọ. Ọkan wa ko balẹ rara, ohun toju wa n ri niluu wa niyẹn. Ko si ọlọpaa, awọn teṣan kekere ti wọn n pe ni ‘police post’ la ni, mẹta pere lo wa ni gbogbo agbegbe yii, Ọlọrun lo n ṣọ wa. Eyi to n sọ pe awọn eeyan wa ko sa lọ si Benin yẹn ko ri bẹẹ rara’’