Olu Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun
Ko din laaadọrin (70) awọn Fulani darandaran ti wọn sa kuro n’Igangan, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa, lẹyin ikọlu ti wọn ṣe sawọn araalu naa ti wọn tun sa wọ Igbẹti, nipinlẹ Ọyọ lọjọ Ẹti to kọja yii ti i ṣe ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa. Ṣugbọn awọn araalu naa ko gba wọn laaye, niṣe ni wọn dawo ọkọ fun wọn pe ki wọn maa lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn Fulani naa ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin, ati ọmọ-ọwọ wọn ni wọn de si Igbẹti pẹlu dukia wọn. Ọkọ akero meji ni wọn gbe wọ ilu naa lati Igangan, ṣugbọn ilu Ilero ni ilẹ ṣu wọn si.
Nigba ti wọn ta Elero tilu Ilero, Ọba Wasiu Saka Olokolonigi, lolobo nipa awọn alejo naa, Kabiyesi yari pe ko saaye fawọn eeyan naa niluu oun. Teṣan ọlọpaa ilu naa ni wọn sun mọju ọjọ keji, ko too di pe wọn tẹkọ leti gba ọna ilu Igboho lọ. Ṣugbọn niṣe ni wọn tun le wọn n’Igboho naa.
Lẹyin naa ni wọn kọri si ọna Igbẹti, bi wọn ṣe debẹ tawọn araalu ri wọn lawọn naa ke si Onigbẹti, Ọba Emmanuel Oyekan Oyebisi, loun naa ba pe Eria Kọmanda agbegbe naa, AC Taiwo Adedeji, ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, pe awọn araalu lo pada sanwo ọkọ tawọn Fulani naa wọ lati ilu Ilero, nigba tawọn dẹrẹba ọkọ to gbe wọn wa yari pe owo ọkọ Igbẹti ni wọn san fawọn.
Alaga ọmọ Igbẹti, Oloye Fashina Alawọde, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni awọn ọmọ ilu naa ni wọn da ẹgbẹrun mẹtala naira fawọn Fulani naa pe ki wọn maa ba tiwọn lọ.
O lawọn gbe igbesẹ yii lati koore Eṣu ni, kohun to ṣẹlẹ n’Igangan ma baa tun ṣẹlẹ.
Adugbo Oko Olowo, loju ọna to lọ si Jẹbba, ni wọn pada fi mọto ko awọn Fulani naa lọ.
Ọkan ninu awọn dẹrẹba to wa wọn lọ, Ọgbẹni Moṣọpẹ Matthew, sọ pe pẹlu iranlọwọ awọn agbofinro bii Sifu Difẹnsi ati Amọtẹkun ni wọn fi sin wọn de adugbo Oko Olowo, loju ọna marosẹ to lọ siluu Jẹbba. Ibẹ ni wọn ja wọn si pe ki wọn maa ba tiwọn lọ