Awọn obi Toyin ti ọrẹkunrin rẹ ge ori rẹ l’Apomu ni: Iru iku ti wọn fi pa ọmọ wa naa ni ki wọn fi pa awọn to pa a

Florence Babaṣọla, Oṣogbo ati Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Akin Clumsy, ẹni tawọn ọlọpaa ti n wa lori iku ọmọdebinrin nni, Toyin Racheal, toun ati Kabiru Oyeduntan jọ ṣeku pa l’Apomu lọsẹ to kọja, ti wọn pa a tan, ti wọn si kun un si wẹwẹ lẹyin ti Akin ba a lo pọ tan.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ṣalaye f’ALAROYE pe ilu Ibadan ti Akin sa lọ ni ọwọ ti tẹ ẹ lẹyin iṣẹ iwadii to lagbara.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni awọn ọlọpaa ṣafihan Kabiru Oyeduntan ni tiẹ, lori ẹsun pe o lẹdi apo pọ mọ Akin lati pa ọrẹbinrin rẹ.

Ṣugbọn bi awọn ọlọpaa ṣe ni awọn yoo foju awọn ọdaran yii wina ofin, bẹẹ lawọn eeyan ọmọ to doloogbe yii naa wa ninu ikaribọnu, ti wọn n fomije ṣaaro Oluwatoyin to kagbako iku ojiji.

Yatọ si iya rẹ, Abilekọ Ṣade Adewale to kọkọ ba ALAROYE sọrọ, ẹni ta a le pe ni baba ọmọ naa bayii, iyẹn Ọgbẹni Adewale Ayinla ati ọga rẹ to n kọṣẹ yaiadirẹsa lọdọ rẹ, Abilekọ Ademọla Fatimọ, naa ba akọroyin wa sọrọ, eyi lohun tawọn eeyan naa wi.

Baba Oloogbe Toyin, Alagba Adewale Ayinla

“Ọmọ mi naa ni mo le pe Toyin, bo tilẹ jẹ pe emi gan-an kọ ni mo bi i. Iya rẹ gbe e waa fẹ mi ni, ko ju bii ọmọ ọdun mẹrin lọ nigba naa, emi ni mo tọju ẹ di ọlọmọge. Ọmọ ọdun mejidinlogun ni.

“Ki i ṣe onijangbọn ọmọ, Ibadan lo wa tẹlẹ to ti n lọ sileewe, o dẹ loun ko lọ mọ, pe oun ko mọwe, oun o si fẹẹ fakoko ṣofo, ohun to jẹ ko maa lọọ kọṣẹ yaidirẹsa nilẹ yii niyẹn.

“Nigba ta a si mu un de, a fi sibi yiadirẹsa, o si n kọ ọ. Nigba to di akoko kan ni iya rẹ ni ko wa soko, ko waa ran oun lọwọ, nitori oko lawa wa. Wiwale to wale ni wahala yii ṣẹlẹ.

“O ti wale lakọọkọ naa to pada, ti iya rẹ ran an niṣẹ. O si tun wa ti eleyii naa, iya rẹ sọ fun un pe ọjọ keji ni ko de o, afi ba a ṣe ri i.

“Ọjọ kẹta pe, mo wa sile ni mo ba ero nita ti wọn ni awọn ri Toyin lori Fesibuuku, pe wọn ti ge e lapa, wọn ge e lẹsẹ, ohun ti emi ri mọ niyẹn o.

“Mi o ri i pẹlu ọkunrin ri, mi o ka ọkunrin kankan pẹlu ẹ ri, nitori ko mu un wale. Mi o le sọ nita o, ṣe ẹ mọ pe obinrin teeyan ko tẹle jade, ko si bẹ ẹ ṣe fẹẹ mọ boya o n dan nnkan kan wo nita, ṣugbọn a o mọ ẹnikankan mọ ọn pe lagbaja to n ba rin ree.

“Baba rẹ to bi i gan-an ti ku tipẹ, latigba ti iya rẹ si ti fẹ mi ni mo ti ni tọju ẹ titi. Iku Toyin gbona lara mi gan-an, mo ro o, mi o ja a rara. Ṣe ẹ mọ pe onbi-ni ko to- onwo-ni. Iya rẹ gan-an wa loko, bi mo ṣe gbọ bayii, mo sare lọọ gbe e wale latoko ni.

“Ko sohun ta a n reti lọdọ ijọba ju idajọ ododo to tọ sawọn to pa wa lọmọ lọ, nitori wọn ti ṣe tiwọn na, a si gbọ pe ọwọ ti ba wọn, ki wọn ṣe ohun yẹ fun wọn lo ku ta a n beere lọwọ ijọba”

 Ṣade Adewale, iya Oloogbe Oluwatoyin

Ọmọ mi niṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, Racheal Oluwatoyin lorukọ ẹ, ipo kẹrin lo wa ninu awọn ọmọ mi. Ọmọ Apomu yii naa ni, ile Araogberu nile wọn, ọmọ ọdun mejidinlogun ni.

“Oko Ẹlẹyẹlẹ ni mo wa, niluu Ikoyi, o ti bẹrẹ iṣẹ yiadirẹsa, mo ran an wale pe ko lọọ ra nnkan ta a maa jẹ wa, ko si de lọjọ keji ni. Mo ṣaa reti-reti, mi o ri i lọjọ keji yẹn.

“Nigba to di lọjọ kẹta, baba wọn wale, nigba ti wọn dele ti wọn gbọ ohun to ṣẹlẹ yii, ara wọn o gba a mọ, bi wọn ṣe tun pada wa soko ti wọn waa gbe mi niyẹn. Bo ṣe jẹ niyẹn o.

“Emi o rọkunrin kankan pẹlu ẹ ri o, Ibadan lo n gbe tẹlẹ ko too di pe o wale. Ko ti i ju oṣu mẹta lọ to de ọdọ mi, niṣe lo ni oun o gbe Ibadan mọ, pe ibẹ ti su oun. Nigba tọmọ ẹni ko si ni i buru buru ka le e fẹkun pa jẹ, mo ni ko maa bọ l’Apomu, ka jọ maa gbe, nitori ẹ ni mo ṣe mu un lọ sibi to ti n kọṣẹ.

“Loootọ lo jẹ pe aarin ọsẹ niṣẹlẹ yii waye, ti ko dẹ si nibi iṣẹ. Ohun to fa a ni pe mo mu un kuro lọdọ ọga rẹ pe ka jọ lọọ ṣiṣẹ loko, ki n le ri ẹgbẹrun mẹwaa ti ọga rẹ fẹe gba fun un. Mo ni ti mo ba tiẹ ṣi ri ẹgbẹrun marun-un fun un na, ara ẹ ni, nitori ẹ ni mo ṣe mu un lọ soko, ki n too ran an wale laarin ọsẹ yẹn.

“Di bi mo ṣe wa yii, ara mi ko si bo ṣe wa tẹlẹ, mi o gbọ nnkan kan nipa awọn to pa a yii ri, ọmọ mi o sọ nnkan kan fun mi ri. Ohun ti mo fẹ bayii ko ju pe bi wọn ṣe pa ọmọ mi yii, kijọba pa awọn naa bẹẹ, kiyaa tiwọn naa foju sunkun wọn.

Leave a Reply