Awọn Fulani to sa lọ si Kwara lati Igangan ti tun fẹẹ rija awọn eeyan abule Okemiri to gba wọn lalejo niluu Oro

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ẹgbẹ kan to jẹ tawọn ọmọ bibi ẹkun Guusu Kwara, iyẹn Kwara South Movement, ti ke si awọn agbofinro ati ijọba lati tẹ ẹ mọ Seriki awọn Fulani tilu Igangan, nijọba ibilẹ Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, Salihu Abdulkadir, ẹni ti ajafẹtọ Yoruba nni, Sunday Adejumọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho atawọn araalu Igangan le jade niluu wọn, leti ko ma kọja aaye rẹ, ko si fọwọ sibi to n gbe niwọnba asiko ti yoo lo ni Kwara to ti n tẹdo.

Ọsẹ to kọja yii ni Sẹriki Fulani Igangan pẹlu awọn ẹbi rẹ atawọn ibatan rẹ digba-dagbọn wa si agbegbe kan labule Buari/Okerimi, nitosi ilu Oro, nipinlẹ Kwara, nibi ti wọn tẹdo si.

Adari ẹgbẹ Kwara South Movement, Saheed Ọlayinka Ọdọfin, ati akọwe ẹgbẹ naa, Adeyinka Adeoye, ni gbogbo eeyan lo mọ Kwara ni ipinlẹ alaafia, ẹnikẹni to ba si fẹẹ da alaafia ilu ru, awọn yoo ṣe ohunkohun lati da onitọhun lọwọ kọ.

“A n lo anfaani yii lati kilọ fun Seriki Fulani Igangan atawọn eeyan rẹ lati ma ṣi ẹsẹ gbe lọwọ asiko ti wọn maa lo, bi bẹẹ kọ, awọn yoo tun le e kuro nibi to tẹdo si naa.

Wọn rọ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lati san ṣokoto rẹ le daadaa lori ipese aabo to peye fun ẹmi ati dukia araalu, kijọba si ri i pe Sẹriki Fulani naa atawọn eeyan rẹ ko lọwọ ninu iwa ọdaran.

Wọn tun ke si awọn agbofinro lati gbaradi daadaa nitori pe ẹgbẹ naa ko ni i foju ree wo ọkunrin naa bi iwa ọdaran kan ba n waye lagbegbe rẹ.

Bakan naa ni ọba ilu Oro ba awọn eeyan ọhun ṣepade laafin rẹ nigba to gbọ pe awọn eeyan naa ti fẹẹ maa tasẹ agẹrẹ lọ sori ilẹ oko awọn eeyan  Abuke Koshoni, to wa ni Okemiri, niluu Oro. Wọn si ṣeleri pe awọn yoo fi ibẹ silẹ laarin ọjọ meje

Leave a Reply