Awọn Fulani yii lo wa nidii gbogbo ijinigbe to waye nipinlẹ Ogun laipẹ yii

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Babuga Abubakar, Umar Usman ati Mohammed Bello, awọn ajinigbe mẹta ti wọn ko awọn eeyan Ayetoro, Ọlọrunda ati Imẹkọ si wahala loṣu to kọja yii niyẹn. Awọn ni wọn ji akẹkọọ meji ọmọ O.A U gbe, wọn ji dokita ati nọọsi lọna Abẹokuta s’Imẹkọ, wọn si tun gbe iya kan, Yẹmi Ojẹdapọ, ni abule Olodo, ẹni ti wọn pa nitori wọn lo da awọn mọ nigba tawọn ji i gbe sa lọ.

Kọmandi ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, ni wọn ti foju awọn ajinigbe naa han l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, lẹyin ti ọwọn tẹ wọn.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko gbọ ede mi-in ju ede Fulfude ti i ṣe ti Fulani ti wọn jẹ lọ, ti awọn mi-in si n sọ Hausa ninu wọn, sibẹ, wọn jẹwọ, awọn ogbufọ to gbọ ede Hausa si n tu u si ede Yoruba ati Geesi fawọn akọroyin, eyi ti ALAROYE naa wa ninu wọn.

Awọn mẹtẹẹta yii jẹwọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2021, awọn ji awọn akẹkọọ obinrin meji gbe lagbegbe Ayetoro, iyẹn awọn ọmọ ileewe Yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ.

Eyi to n jẹ Abubakar Babuga, ẹni ogoji ọdun, ṣalaye pe ki i ṣe awọn akẹkọọ yii lawọn fẹẹ ji gbe lọjọ naa, o ni obinrin to n ta kaadi ipe lọpọ yanturu nitosi ibẹ lawọn wa lọ, nigba tawọn ko ri iyẹn gbe lawọn gbe awọn akẹkọọ meji naa.

Bakan naa ni wọn ṣalaye pe lọjọ keje, oṣu kẹrin, ọdun yii, lawọn gbe dokita ati nọọsi labule Olubọ, loju ọna Abẹokuta Imẹkọ.

Ni ti Abilekọ Yẹmi Ọjẹdapọ, wọn ni Muhammed Bello lo pe awọn yooku pe kawọn waa ji i gbe, oun naa lo si ṣeto bawọn ṣe pa a nigba to mọ pe obinrin naa da oun atawọn yooku mọ.

Koda, foonu ti wọn fi n pe ẹbi awọn ti wọn ji gbe pe ki wọn mowo wa ṣi wa lọwọ wọn nigba ti awọn ọlọpaa mu wọn laipẹ yii, wọn ṣẹṣẹ gba a lọwọ wọn lẹyin tọwọ ba wọn ni.

Lọjọ yii kan naa ni wọn ṣafihan awọn to ji Olori ilu Imọpẹ, n’Ijẹbu-Igbo, gbe, iyẹn Oloye Tajudeen Ọmọtayọ. Ogunjọ, oṣu kẹta, ni wọn ji baba naa gbe, miliọnu lọna ọgọrun-un kan naira la si gbọ pe wọn gba ki wọn too fi i silẹ.

Awọn to wa nidii ijinigbe eyi ni: Nura Bello, ọmọ ọdun mọkanlelogun (21) ati Abubakar Bello Amọdu, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn(26)

Leave a Reply