Awọn gomina PDP marun-un to n binu pade nibi ipolongo ibo Makinde n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina mẹrin ọtọọtọ, lati apa Ila-Oorun orileede yii, Gomina Samuel Ortom, ti ipinlẹ Benue; Okezie Ikpeazu (Abia); Ifeanyi Ugwuanyi (Enugu), ati Nyesom Wike, ti i ṣe gomina ipinlẹ Rivers ni wọn peju pesẹ sibi iṣide ipolongo ibo gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati dupo gomina fun saa keji ninu idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

ti wọn si ṣeleri lati lo ipo ati agbara wọn lati ṣatilẹyin fun gomina naa ko le wọle idibo lati ṣe saa keji lori aleefa.

Ṣugbọn awọn gomina yii ja awọn eeyan ni tanmọ-ọn pẹlu bi wọn ṣe kọ lati mu ileri wọn ṣẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria nibi eto naa to waye ni gbangba ita gbọgan Mapo, n’Ibadan, pe awọn yoo darukọ ẹni ti awọn yoo ṣatilẹyin ibo aarẹ fun.

Gomina Wike, Ortom, Ikpeazu ati Ugwuanyi pẹlu Gomina Makinde tipinlẹ Ọyọ ni wọn kọyin si ibi ti apapọ ẹgbẹ Alaburada (PDP), kọju si lori ọrọ idibo aarẹ orileede yii, wọn ni awọn ko ni i ṣatilẹyin fun Alhaji Atiku Abubakar, ẹni to n dupo aarẹ ilẹ yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu awọn lati ṣaṣeyọri ninu idibo aarẹ to n bọ lọna yii laelae.

Ṣaaju, iyẹn ni nnkan bii ọjọ mẹta sẹyin lawọn gomina tinu n bi ninu ẹgbẹ oṣelu wọn yii ti ṣeleri pe nibi eto ipolongo idibo Gomina Makinde, n’Ibadan, lawọn yoo ti kede ẹni tawọn yoo ṣiṣẹ fun ninu awọn to n dupo aarẹ orileede yii.

Ẹnu Gomina Wike to jẹ adari awọn gomina yii lawọn eeyan ro pe awọn yoo ti gbọ iroyin naa, ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa pada ṣọrọ nibi eto ọhun, o ni asiko ọrọ ko ti i to, bi asiko ọrọ ba si to paapaa, ki i ṣe ẹnu oun ni wọn yoo ti gbọ ọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Oloootọ ni Makinde. Ohun to ba sọ lo maa n tẹle. Idi niyẹn ti ẹyin ara ipinlẹ Ọyọ fi gbọdọ dibo fun un lati ṣe saa keji nitori gbogbo ileri to ba ṣe lo maa mu ṣẹ.

“Ẹgbẹ oṣelu PDP la maa ṣiṣẹ fun ninu idibo gomina atawọn ipo aṣofin gbogbo. Nitori naa, ẹgbẹ PDP ni kẹ ẹ dibo yin fun. Ṣugbọn to ba digba idibo aarẹ, gomina yin (Makinde) aa maa ṣọ ibi tẹ ẹ maa lọ fun yin”.

Eyi ko dun mọ awọn kan ninu ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun kan ninu, bi Wike si ṣe sọrọ naa lawọn ololufẹ Atiku to wa nibẹ bẹrẹ si i pariwo, “Aatiiku!  Aatiiku! Aatiiku”!

Nigba to n sọ awọn ara ipinlẹ Ọyọ lati fi ibo wọn gbe oun wọle fun saa keji nipo gomina, Gomina Makinde sọ pe ko si nnkan naa ti oun ṣeleri lasiko ipolongo idibo oun lọdun 2019 ti oun ko ti i mu ṣẹ.

Ọba Orin, Saheed Oṣupa ati Alhaji Taye Adebisi Currency ni wọn fi orin da awọn eeyan laraya nibi eto naa.

Lara awọn to wa nibẹ ni Igbakeji alaga ẹgbẹ PDP lẹkun ilẹ Yoruba, Alhaji Taofeek Arapaja, ẹni to gbe asia ẹgbẹ PDP le Makinde atawọn to n dupo aṣofin nipinlẹ Ọyọ ati aṣofin ijọba apapọ lọwọ; minisita fun idagbasoke olu ilu ilẹ yii nigba kan, Oloye (Abilekọ) Jumọkẹ Akinjide; olori awọn oṣiṣẹ gomina lasiko iṣejọba Oloogbe Gomina Adebayọ Alao-Akala, Dokita Saka Balogun ati bẹẹ bẹẹ lọ, titi dori gbogbo awọn to n dupo lọlọkan-o-jọkan ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Lopin ọsẹ yii, iyẹn lọjọ Abamẹta, Satide, leto ipolongo idibo ọhun yoo tun tẹsiwaju nigba ti igbimọ ipolongo Makinde yoo lọ siluu Igboọra, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, lati tun beere fun atilẹyin awọn ara agbegbe Oke-Ogun ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply