Awọn Ibo kọlu ọmọ wọn to gbe awọn olorin lọ si kootu nitori ọrọ SARS

Aderounmu Kazeem

Lati ana Wẹsidee, Ọjọruu, ti iroyin ti gba igboro kan pe ọkunrin ajafẹtọọ-ọmọniyan, Kenechukwu Okeke, ti pe awọn eeyan kan lẹjọ lori rogbnodiyan ọrọ SARS ni oriṣiiriṣi awuyewuye ti n jẹyọ lori ọrọ naa.

Ni bayii, ẹgbẹ kan to jẹ ẹgbẹ ọdọ awọn ẹya Ibo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọkunrin yii, wọn ni awọn ko lọwọ si i rara lori bo ṣe pe awọn olorin, awọn oṣere tiata, agbaboọolu, pasitọ atawọn mi-in lẹjọ nitori ti wọn ṣe ṣatilẹyin fawọn to ṣewọde SARS.

Ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Maduabuchi Nwodo, fọwọ si lo ti sọ pe igbesẹ ti ọkunrin ajafẹtọọ ọhun gbe ko bojumu rara lasiko yii, o si fi kun un pe awọn ko lọwọ si i rara.

Ṣiwaju si i, awọn ẹya Ibo yii ti sọ pe awọn eeyan kan lo n lo ọkunrin naa lati fi yẹyẹ ijọba Buhari loju awọn orilẹ-ede mi-in lagbaaye.

Eeyan bii aadọta ni Okeke gbe lọ sile-ẹjọ, ẹsun to si fi kan wọn ni pe awọn gan-an ni wọn ṣatilẹyin fawọn to ṣewọde, ninu eyi ti wọn ti ba dukia oun jẹ niluu Abuja nigba ti nnkan yiwọ, tawọn janduku ja iwọde ọhun gba mọ wọn lọwọ

Lara awọn ti ọkunrin yii pe lẹjọ ni Pasitọ ṣọọṣi Daystar, Sam Adeyemi; Aisha Yesufu; Kanu Nwankwo; Joe Abah; Kiki Mordi, Yul Edochie, Debo Adedayọ; Maryam Akpaokagi, Folarin Falana, Banky W, atawọn mi-in.

 

Leave a Reply