Awọn ileewe yoo berẹ pada lọjọ Aje nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ lasiko tawọn ọdọ n fẹhonu han lori SARS, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnijinnia Ṣeyi Makinde, ti pasẹ pe ki awọn ileewe wọle pada kaakiri ipinlẹ naa ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto ẹkọ ati imọ ẹrọ,lasunkanmi Ọlaleyẹ, fi sita ni gomina ti kede ọrọ naa ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

O fi kun un pe igbesẹ yii waye nitori pe ohun gbogbo ti rọlẹ nipinlẹ Ọyọ. Niwọn igba ti gomina si ti ṣeleri pe oun yoo ṣe agbeyẹwo bi ohun gbogbo ba ṣe ri lọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, lati le mọ boya ileewe yoo ṣi pada tabi bẹẹ kọ, ti ko si si wahala kankan mọ lo fi paṣẹ iwọle awọn akẹkọọ.

Makinde ni niwọn igba ti ohun gbogbo ti rọlẹ, ko si ohun to ku ju ki awọn akẹkọọ pada sileewe, ki wọn si maa ba iṣẹ wọn lọ.

O waa rọ awọn eeyan naa lati lepa alaafia, ki wọn si nma fa wahala kankan.

Leave a Reply