Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin yii, ni awọn janduku kan ti wọn wọ aṣọ dudu, ya bo ile Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma. Wọn dana sun ile ọhun to wa ni Omuma, wọn si yinbọn pa meji ninu awọn ẹṣọ to n ṣọ ọ, bẹẹ ni wọn dana sun awọn mọto to wa ninu ọgba ile gomina pẹlu.
Nnkan bii aago mẹsan-an aarọ lawọn agbebọn naa de ba a ṣe gbọ, bi wọn si ṣe n bọ ni wọn ni wọn ti kọkọ yinbọn fun awọn eeyan meji kan ti wọn ba pade loju ọna to lọ si ile gomina yii, eyi to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Oru, nipinlẹ Imo.
Bi awọn agbebọn naa ṣe de, awọn ẹṣọ ile gomina bẹrẹ si i yinbọn soke lati le wọn lọ, ṣugbọn ọwọ awọn agbebọn ọhun ju tiwọn lọ. Awọn janduku naa mu oṣiṣẹ aṣọle gomina meji mọlẹ, Sifu Difẹnsi tilẹ ni ọkan ninu wọn, bi wọn ṣe fibọn da ẹmi wọn legbodo niyẹn.
Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Imo, Declan Emelumba, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni meji ni oṣiṣẹ alaabo gomina to ku, ki i ṣe pe wọn pọ rẹpẹtẹ bawọn kan ṣe n gbe e kiri.
Awọn agbebọn naa to mẹẹẹdogun gẹgẹ ba a ṣe gbọ, mọto mẹta to tẹle ara wọn lọwọọwọ ni wọn gbe wa. Ọkọ tipa (tipper) kan naa tẹle wọn, aloku taya ni wọn ko sinu ẹ bamu, bo ṣe di pe wọn ṣina bolẹ niyẹn
Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to le sọ pato ibi ti ikọlu yii ti wa, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe yoo lọwọ kan oṣelu ninu.