Awọn janduku la yin taju-taju si, ki i ṣe awọn to n ṣewọde EndSARS-Kọmiṣanna ọlọpaa Eko

Jọkẹ Amọri

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti ṣalaye pe ki i ṣe awọn ti wọn n ṣewọde iranti ọdun kan iṣẹlẹ EndSARS lawọn agbofinro yin taju-taju ti wọn n pe ni (teargas) mọ, bi ko ṣe awọn janduku. O ni awọn to n ṣewọde ti fi ibẹ silẹ ki awọn ọlọpaa too yin taju-taju naa.

Odumosu sọrọ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Too-geeti Lekki ti iwọde ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni iranti wahala to ṣẹlẹ lọdun to kọja, leyii ti ọpọ awọn ọdọ kan ti ku, ti ọpọ si fara pa lasiko ti awọn ṣọja yinbọ lu wọn.

O ni ohun to jẹ ki awọn yin tajutaaju sawọn eeyan naa ni pe awọn to n ṣewọde yii ti sọ pe aago mẹjọ si mẹwaa aarọ lawọn yoo fi ṣe e. Adehun ti wọn si ṣe pẹlu awọn ni pe ninu mọto lawọn maa wa tawọn ti maa to lọwọọwọ lati ṣe iranti naa, bẹẹ gẹlẹ ni wọn si ṣe.

Odumosu ni bẹẹ ni wọn sọ fun awọn pe ẹnikẹni tawọn ba ri to n lọ tabi to n bọ ni agbegbe naa lẹyin aago mẹwaa aarọ ki i ṣe ara awọn, idi niyi tawọn si fi yin tajutaju si awọn ti awọn ri nibẹ. O ni janduku ni awọn eeyan naa, niṣe ni wọn waa jale, ti wọn si fẹẹ da wahala silẹ. ‘Nigba ta a mu wọn, oriṣiiriṣii nnkan ija oloro la ba lara wọn bii ọbẹ, ada. Idi ta a fi le wọn niyi, ki wọn ma baa da wahala silẹ, a ko si fẹ ki wọn di awọn araalu lọwọ lati maa ba iṣẹ wọn lọ.’ Bẹẹ ni Ọga ọlọpaa Eko naa sọ.

Leave a Reply