Awọn janduku ya wọ ileeṣẹ redio Amuludun n’Ibadan, wọn ba mọto ati dukia jẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn oniṣẹ ibi to kọ lu ileeṣẹ redio ijọba apapọ, Amuludun FM, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ nibẹ.

Eto aabo ipinlẹ Ọyọ dẹni kọlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a lo tan yii, pẹlu bi awọn tọọgi kan ṣe dihamọra ija, ti wọn si kọ lu ileeṣẹ redio ijọba apapọ ilẹ yii, iyẹn Amuludun FM, to wa laduugbo Mọniya, n’Ibadan.

Koko ohun to si fa ikọlu ọhun ko ti i ye ẹnikẹni di baa ṣe n wi yii. Ẹnikan to ta akọroyin wa lolobo iṣẹlẹ yii fidi ẹ mulẹ pe ara ija lawọn ọbayejẹ eeyan naa mu lọ sileeṣẹ ijọba yii nitori niṣe ni wọn dihamọra pẹlu awọn nnkan ija oloro mi-in lọọ huwa apa ọhun.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio yii sọ fawọn oniroyin pe ọkẹ aimọye dukia bii ọkọ ayọkẹlẹ, ferese ati bẹẹ bẹẹ lọ  ni wọn bajẹ nileeṣẹ redio naa.

Ọga agba Redio Amuludun, Ọgbẹni Niyi Dahunsi, fidi iroyin yii mulẹ. O ni awọn ti ranṣẹ pe awọn eleto aabo lati waa daabo bo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa nigba ti awọn agbofinro n ṣewadii lọwọ lati mọ awọn basejẹ eeyan to huwa apa yii.

Leave a Reply