Jọkẹ Amọri
Gbogbo awọn olugbe awọn adugbo bii Bọrọbọrọ, Oriawo ati Abolongo, niluu Ọyọ, ko le sun oorun asundiju lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, pẹlu bi awọn agbebọn kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ ṣe ya wọ ọgba ẹwọn to wa ni Oriawo, niluu Ọyọ, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ.
Wahala naa pọ debii pe ọpọ awọn ẹlẹwọn yii lo fara pa. Loootọ ni awọn kan raaye sa lọ, bẹẹ ni wọn si mu awọn mi-in ninu awọn ẹlẹwọn to sa lọ ọhun.
Gẹgẹ bi ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣe fi to akọroyin wa leti, wọn ni ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ lawọn n sadeede gbọ iro kan to lagbara. Wọn ni kinni naa ko jọ iro ibọn rara, bii bọmbu lo ṣe n dun gboa gboa, eyi to ko ipaya ati ibẹrubojo ba awọn olugbe agbegbe naa.
Ọkunrin yii sọ pe niṣe ni idarudapọ ba gbogbo adugbo Bọrọbọrọ ati Oriawo ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, niṣe ni onikaluku si n sa kijokijo. O ni nigba ti iro nla nla naa ko dawọ duro lawọn ọkunrin to laya ya bo oju titi, ti wọn fẹẹ mọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an.
Nigba naa ni wọn too mọ pe ọgba ẹwọn to wa ni Abolongo ni awọn agbebọn kan ṣakọlu si, ti wọn ni wọn fẹẹ tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ nibẹ.
ALAROYE gbọ pe awọn oluṣọ ọgba ẹwọn naa paapaa ko kawọn gbera, nitori niṣe ni awọn pẹlu awọn agbebọn yii kọju ibọn sira wọn.
Lasiko naa ni awọn ẹlẹwọn kan raaye sa jade, bẹẹ ni awọn kan si fara pa pẹlu.
A gbọ pe wọn ri diẹ ko pada ninu awọn to sa jade ọhun, ṣugbọn awọn kan sa lọ, ko si ti i sẹni to mọ iye awọn ti wọn raaye sa lọ ọhun.
Lasiko rogbodiyan naa ni wọn ni awọn kan ya wọ adugbo Oriaawo ati Bọrọbọrọ, ti wọn si bẹrẹ si i ja awọn eeyan lole. Awọn araadugbo naa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn janduku ọhun tabi awọn ẹlẹwọn ti wọn sa kuro lọgba ẹwọn ni wọn pitu naa. Mọto mẹjọ la gbọ pe wọn ji lawọn adugbo ọhun pẹlu bi wọn ṣe n wọ awọn ile onle, ti wọn si n fipa ji ọkọ wọn lọ.
ALAROYE gbọ pe awọn eeyan ti wọn ji mọto wọn ti lọọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti ni agọ ọlọpaa to wa ni Durbar, niluu Ọyọ. Bẹẹ ni wọn ni awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa ti n ṣayẹwo ibi ti nnkan de duro lori iṣẹlẹ naa.