Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari ipa ti wọn ko ninu rogbodiyan to waye lasiko ti wọn n ṣe iwọde SARS l’Okitipupa, Adajọ kootu Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti ni kawọn ọkunrin mẹrin kan ṣi wa lọgba ẹwọn na.
Awọn olujẹjọ ọhun, Okiriji Sunday, Oyewọle Ọlalẹyẹ, Ọmọtubora Iyanu ati Ọlawọle Gbenga, ni wọn fẹsun marun-un ọtọọtọ kan lasiko ti wọn n fara han nile-ẹjọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Awọn iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, nigba ti ofin konilegbele oniwakati mẹrinlelogun tijọba pasẹ rẹ ṣi wa nita.
Ẹsun akọkọ ti wọn ka si awọn afurasi mẹrẹẹrin naa lẹsẹ ni pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe dana sun tesan ọlọpaa mẹta, ọpọlọpọ ọkọ, awọn ẹru ofin to wa ni teṣan, kootu Majisreeti, ile-ẹjọ giga, sẹkiteriati ijọba ibilẹ Okitipupa ati ṣiṣe akọlu sọgba ẹwọn ilu ọhun, nibi ti wọn ti tu ọgọọrọ awọn ẹlẹwọn silẹ.
Yatọ si awọn ẹru ijọba bii aṣọ ọlọpaa, ìbọn, ọkada tuntun atawọn nnkan mi-in ti wọn ji ko, wọn lawọn olujẹjọ naa tun gbiyanju lati paayan pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ sun ọlọpaa kan, Falọdun Lawrence, atawọn ẹbi rẹ mọ ile ijọba ti wọn n gbe niluu Okitipupa.
Gbogbo ẹsun yii ni wọn lo lodi patapata, to si tun ni ijiya to lagbara labẹ ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Ọlọpaa agbefọba, Suleiman Abdulateef, lo kọkọ dabaa fífi awọn olujẹjọ ọhun pamọ sọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa la ti ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye lati ọdọ awọn agbẹjọro mẹtẹẹta to n gbẹnusọ fun wọn, Abilekọ T. A. A. Oyedele gba ẹbẹ agbefọba wọle.
O ni kawọn afurasi naa ṣi lọọ maa ṣere wọn ninu ọgba ẹwọn to wa niluu Ọwọ titi dọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2020.