Florence Babaṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti wọ awọn mẹta lọ sile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan.
Awọn afurasi naa ni: Aishat Mutiu, ẹni ọdun mọkanlelogun, Oyewale Ṣẹgun, ẹni ọdun mejilelogun ati Ijaye Shọla, ẹni ọdun mejilelogun atawọn mi-in ti wọn ti sa lọ bayii ni wọn fi ẹsun mẹrin kan.
Awọn ẹsun mẹrẹẹrin naa ni igbimọ-pọ huwa buburu, idigunjale ati ipaniyan. Agbefọba, ASP Idoko John, sọ fun kootu pe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ni wọn huwa naa laago mọkanla aarọ nileeṣẹ TUNS International Holding Limited, niluu Oṣogbo.
Idoko fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu ibọn, ada, irin, igi atawọn nnkan ija mi-in ni wọn ko lọ sibẹ. Wọn ja Taofeek Ọlakunle lole awọn nnkan bii kọmputa, tẹlifiṣan, baagi iyọ, baagi fulawa, masinni ti wọn fi n ge burẹdi, maṣinni ti wọn fi n ṣe guguru ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni awọn olujẹjọ yii yinbọn fun ẹnikan to n jẹ Abdulrasheed Ọlawale, to si pada yọri si iku rẹ.
Idoko ni awọn iwa naa lodi si abala ikẹfa, ikeji, okoolelọọọdunrun-un o le mẹrin (324) ati okoolelọọọdunrun-un o din ẹyọ kan (319) ofin iwa idigunjale ati gbigbe nnkan ija oloro rin ti orileede Naijiria ati abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lẹyin ti awọn mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi ni awọn agbẹjọro wọn, Taiwo Awokunle, Oloye Bọla Abimbọla Ige, A. A. Adelowo ati A. O. Olodo bẹbẹ fun beeli wọn lọna irọrun.
Adajọ Modupẹ Awodele paṣẹ pe ki wọn ko awọn olujẹjọ lọ si ọgba ẹwọn Ileṣa. O ni ki agbefọba gbe faili wọn lọ si ẹka eto idajọ l’Ọṣun.
O waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu kejila, ọdun yii, bẹẹ lo taari ẹjọ wọn si Majisreeti Kẹta.