Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni eto adura pataki kan waye fun ọmọ bibi ilu Omu-Aran, Adeoye Owolẹwa, ẹni to jawe olubori ibo lati ṣoju ẹkun Columbia nile aṣofin ilẹ Amẹrika.
Awọn ẹbi pẹlu aṣọ ẹgbẹjọda ni wọn Ṣeto adura naa fun aṣeyọri ọkunrin ọhun nipo tuntun to ṣẹṣẹ bọ si.
Imaamu agba ilu Omu-Aran, Alhaji Sọdiq Alalobo, lo dari eto adura naa to waye ninu agboole Owolẹwa to wa ni Igangu, l’Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara. O ka ẹsẹ kuraani kan lati gbe adura rẹ lẹyin, o bẹbe pe ki Ọlọrun tubọ fun Owolẹwa ni ọpọlọpọ aṣeyọri.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa, Olomu tilu Omu-Aran, Ọba Abdulraheem Adeoti, ẹni ti Eesa Omu-Aran, Oloye Jide Adebayọ ṣoju fun, ni inu oun dun fun aṣeyọri naa, paapaa bo ṣe jẹ igba akọkọ ti ọmọ orilẹ-ede yii yoo de iru ipo bẹẹ nilẹ Amẹrika.
Kabiyesi gbadura ki Ọlọrun tẹsiwaju lati maa mu ohun rere bẹẹ waye lasiko toun wa lori aleefa. O lo anfaani naa lati ṣe adura fun gbogbo ọmọ bibi ilu Omu-Aran, nile, loko ati lẹyin odi, fun aṣeyọri alailẹgbẹ yii.
Ẹni to gbẹnusọ fun mọlẹbu naa, Alhaji Funshọ Owolẹwa, ni idile Owolẹwa lo maa n saaba ṣaaju ninu gbogbo ohun to dara tawọn eeyan le rokan.
O ni ki Ọlọrun tubọ ṣe igbega fun ẹbi naa, nitori pe oun nigbagbọ pe awọn ohun ọtun to tun ga ju eyi lọ ṣi n bọ lọna.
Lẹyin eto adura naa ni gbogbo ẹbi kọwọọ jo lọ si aafin kabiyesi tilu tifọn lati ba a yọ fun aṣeyọri to ṣoju rẹ naa.