Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn mọlẹbi Pasitọ Morris Ọlagbaju Fadehan, to jẹ oluṣọ ni ijọ Celestial Church of Christ, Grace of Comfort Parish, Omitótó, ni Ilode, niluu Ileefẹ, ẹni ti igbakeji rẹ, Lekan Ogundipẹ, gun pa, ti rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria lati ri i daju pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ lori iṣẹlẹ naa.
Wọn ke si ọga agba funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, awọn ajọ agbaye to n ja fun ẹtọ ọmọniyan pẹlu awọn lajọlajọ ti ki i ṣe tijọba lati dide iranwọ fun wọn, nitori awọn alagbara kan ti fẹẹ fi ọwọ ọla gba awọn loju.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti sọ pe bo ṣe jẹ pe ẹni kan ṣoṣo lawọn ọlọpaa ri mu lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ko dun mọ awọn ninu rara.
Wọn ni ko sẹni ti ko mọ ninu ijọ naa pe Lekan ni awọn alatilẹyin ti wọn jọ maa n gbogun ti oloogbe naa nibẹ, ko si ṣee ṣe ko jẹ oun nikan lo pa baba naa, to si tun dana sun un laaarọ ọjọ ọhun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, “A gbagbọ pe ti awọn ọlọpaa ba gbiyanju lati ṣewadii to muna doko siwaju si i, ọpọ awọn ti wọn ṣiṣẹ laabi yii pẹlu Lekan lọwọ maa tẹ.
“Latigba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ, oniruuru ipe ajeji la n gba, bẹẹ ni wọn n dunkooko mọ wa lori foonu pe ẹmi wa ko gbe nnkan ti a dawọ le yii.
“Bi awọn oloṣelu kan nipinlẹ Ọṣun ṣe tun deede gbe ọrọ naa kari jẹ iyalẹnu fun wa. Loootọ, a ko ni ẹnikankan bii alafẹyinti, ṣugbọn a mọ pe ti awọn ọmọ Naijiria ba dide ran wa lọwọ, idajọ ododo yoo waye.
“Latigba ti wọn ti da wa loro yii, nnkan ko rọgbọ rara ninu idile wa, aaye ti oloogbe fi silẹ nira fun ẹnikẹni lati di, idi niyẹn ti a fi n rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria lati gba wa, ki iya yii ma jẹ wa gbe, ki awọn ọlọpaa ṣa gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iwa buburu yii, ẹlẹṣẹ kan ko si gbọdọ lọ lai jiya”.