Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ Abilekọ Olagbẹgi tile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, nijọba ibilẹ Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn foju awọn marun-un kan ba. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe lọdun to kọja ni wọn lẹdi apo pọ laarin ara wọn lati ja Ọgbẹni Sunday Ahize, ọmọ Ibo kan to n gbe lagbegbe Agric, niluu Ikorodu, lole dukia rẹ.
Awọn afunrasi ọdaran ọhun ti wọn foju wọn bale-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni: Ogbẹni Joel, Chibuzo ati Rafael, nigba tawọn meji yooku ko wa sile-ẹjọ lasiko ti igbẹjọ wọn n lọ lọwọ.
ALAROYE gbọ pe awọn dukia bii paanu ikọle atawọn dukia mi-in to jẹ ti olupẹjọ ni awọn afurasi ọdaran ọhun lọọ ji ko ninu ọgba ile rẹ to n kọ lọwọ.
Lọsẹ to kọja ti igbẹjọ waye lori ẹjọ naa, adajọ ni ki olupẹjọ ati olujẹjọ lọọ wa ọna lati pari ija naa laarin ara wọn, ki wọn lọọ feegun otolo to ọrọ ija naa. Olupẹjọ ran lọọya rẹ sawọn olujẹjọ pe apapọ owo nnkan tawọn olujẹjọ ji lakata oun jẹ miliọnu meje aabọ Naira, ṣugbọn oun gba ki wọn san miliọnu marun-un Naira, ti wọn ba fẹ ki awọn fi ẹsẹ ile to ọrọ naa gẹgẹ bi Onidaajọ Ọlgbẹgi ṣe sọ. Ṣugbọn loju-ẹsẹ lawọn olujẹjọ ti ni awọn ko le san ju miliọnu kan Naira lọ.
Olupẹjọ paapaa si yari pe oun ko le gba iye ti wọn ni aọn fẹẹ san yii nitori aọn ohun ikọle ti wọn ko ninu ile naa ju iye ti wọn sọ pe awọn fẹẹ san yii lọ. Nigba ti awọn igun mejeeji ko ri ọrọ ọhun yanju ni wọn ba tun ko ara wọn wa sile-ẹjọ lọsẹ yii pe ki adajọ kuku bawọn fẹsẹ ofin to ọrọ naa.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Ọlagbẹgi sun igbẹjọ mi-in si.